Ajé, 10 Oṣù Bélú , 2025
Remove ads
Most read


Nàìjíríà
orílẹ̀-èdè olómìnira ní Ìwọ̀òrùn Áfríkà
Nàìjíríà jẹ́ Orílẹ̀-èdè Olómìnira Ìjọba Àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà jẹ́ orílẹ̀-èdè ìjọba àpapọ̀ olómìnira tí ó ní ìjọba ìpínlẹ̀ mẹ́rindínlógójì tó fi mọ́ Agbẹ̀gbẹ̀ Olúìlú Ìjọba Àpapọ̀. Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wà ní apá Iwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Áfríkà. Orílẹ̀-èdè yí pààlà pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Benin ní apá ìwọ̀ Oòrùn, ó tún pààlà pẹ́lú orílẹ̀-èdè olómìnira ti Nijẹr ní apá àríwá, Chad àti Kamẹróòn ní apá ìlà Oòrùn àti Òkun Atlantiki ni apá gúúsù. Abuja ni ó jẹ́ Olú-Ìlú fún orílẹ̀-èdè náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Nàìjíríà ní ẹ̀yà púpọ̀, àwọn ẹ̀yà mẹ́ta ni wọ́n hànde tí wọ́n tóbi jùlọ, tí wọ́n sì pọ̀ jùlo, tí a sì kó àwọn ẹ̀ka ìsọ̀rí ìsọ̀rí èyà tókù sí abẹ́ wọn. Àwọn wọ̀nyí ni Ẹ̀ya Hausa, Ẹ̀ya Ìgbò ati Yorùbá.
144 views
Show more















