Àìsàn inú afẹ́fẹ́
From Wikipedia, the free encyclopedia
Àìsàn inú afẹ́fẹ́ tàbí atẹ́gùn jẹ́ àìsàn kí àìsàn tí kòkòrò afàìsàn lè fà tí ẹ̀rún rẹ̀ nínú atẹ́gùn lè ṣàkóbá fún ẹlòmíràn bí wọ́n bá mí í sínú.[2] Ògùn irú àìsàn báyìí ṣe pàtàkì sí ènìyàn àti ẹranko. Àwọn kòkòrò afàìsàn náà lè jẹ́ kòkòrò ààrùn-ẹ̀ràn, bakitéríà, tàbí fọ́nńgaì tí wọ́n lè ràn káàkiri nípa èémí, ọ̀rọ̀ sísọ, ikọ́ wúwú, èésín sí sín, pípo eruku, fífọ́n nǹkan olómi ká, tàbí ìṣe tó bá ń fa ẹ̀rún inú atẹ́gùn tàbí nǹkan tó lè fọ́nká nínú atẹ́gùn.
Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, àwọn ẹ̀rún àìsàn nínú atẹ́gùn máa ń fa àrùn láti imú, ọ̀fun, sinuses, àti ìfun, èyí ló máa ń fa ikọ́, ọgbẹ́ ọ̀fun àti àwọn àmìn àwọn àìsàn míì tó lè ṣẹ́yọ lágọ̀ọ́ ara.
Lára àwọn gbajúmọ̀ àrùn inú afẹ́fẹ́ ni : ẹ̀ràn kòrónà, àrùn ilẹ̀ gbígbóná, morbillivirus, àrùn ilẹ̀ tútù, ikọ́ fée tàbí ikọ́ àwúgbẹ, Mycobacterium tuberculosis, influenza virus, enterovirus, norovirus, àti, adenovirus, èyí kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ àti respiratory syncytial virus. Irúfẹ́ àwọn àrùn ẹ̀ràn wọ̀nyí nílò afẹ́fẹ́ àyíká àdáwà nígbà ìtọ́jú.