Òmuò-Òkè-Èkìtì
From Wikipedia, the free encyclopedia
Ìlú Òmùò-Òkè Èkìtì jẹ́ ìlú ńlá kan tí ó wà ní apá Ìlà oòrùn Èkìtì ni Òmùò òkè wà. Ìjọba ìbílẹ̀ ìlà Oòrùn ni ìpínlẹ̀ Èkìtì ni Òmùò-òkè tẹ̀dó sí. Òmùò-òkè tó kìlómítà méjìlélọ́gọ́ọ̀rin sí Adó-Èkìtì tí ó jé olú-ìlú ìpínlẹ̀ Èkìtì. Òmùò-òkè ni ìpínlẹ̀ Èkìtì parí sí kí a tó máa- lọ sí ìpìnlẹ̀ Kogi. Ìdí nìyí tí ó fi bá àwọn ìlú bí i, Yàgbà, Ìjùmú, Ìyàmoyè pààlà. Bákan náà ni ó tún bá Erítí Àkókó pààlà ní ìpínlẹ̀ Oǹdó. Ìwádìí fihàn wí pé àwọn ìlú bí Ejurín, Ìlíṣà, Ìṣàyà, Ìgbèṣí, Àhàn, Ìlúdọ̀fin, Orújú, Ìwòrò, Ìráfún ni ó parapọ̀ di Òmùò òkè, Ọláitan àti Ọládiípò (2002:3) Iṣẹ́ òòjọ́ wọn ni iṣẹ́ àgbẹ̀ àti òwò ṣíṣe. Ìdí ti wọn fi ń ṣe iṣẹ́ òwò ni wí pé, Òmùò òkè ni wọn ti máa ń kò ẹrù lọ sí òkè ọya. Ẹ̀ka èdè Òmùò-òkè yàtọ̀ sí Òmùò kọta Òmùò Ọbádóore. Òmùò Èkìtì jẹ́ àpapọ̀ ìlú mẹ́ta. [1] [2]
- Òmùò-òkè Èkìtì
- Òmùò kọta
- Òmùò Ọbádóore
Èdè Òmùò-òkè farapẹ́ èdè Kàbbà, Ìgbàgún àti Yàgbàgún ni ìpinlẹ̀ Kogi. O ṣe é ṣe kí èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí Òmùò-òkè ló bá ìpínlẹ̀ Kogí pààlà. Bákan náà ni àwọn ènìyàn Òmùò-òkè máa ń sọ olórí ẹ̀ka èdè Yorùbá àti èdè Gẹ̀ẹ́sì ni pàápàá àwọn tó mọ̀ọ̀kọ̀-mọ̀ọ́kà.