Adìyẹ

From Wikipedia, the free encyclopedia

Adìyẹ
Remove ads

Taxonomy not available for Gallus; please create it automated assistant

Quick facts Gallus gallus domesticus, Ipò ìdasí ...

Adìyẹ (Gallus gallus domesticus) jẹ́ ẹ̀yà ẹyẹ àti ẹranko ilé tí a ń sìn ní ilé tí wọ́n sì pín sí ẹ̀yà oríṣiríṣi bíi; grey and the Ceylon junglefowl[1] tí a lè rí ní apá Southeastern Asia. A lè akọ adìyẹakọ tàbí kí a pèé ní Àkùkọ yálà èyí tí ó ti dàgbà tàbí èyí ó ṣẹ̀sẹ̀ ń dàgbà bọ̀. Èyí tí ó jẹ́ abo ni a lè pe ní abo adìyẹ tàbí obí yálà èyí tí ó ti dàgbà tàbí èyí tí ó ń dàgbà bọ̀. Ìran ọmọnìyàn ń sin adìyẹ yálà abo tàbí akọ gẹ́gẹ́ bí ounjẹ yálà nípa jíjẹ ẹran wọn tàbí jíjẹ ẹyin tí wọ́n bá yé sílẹ̀.

Nínú gbogbo ẹranko tàbí ẹyẹ oko tabi ilé, adìyẹ ni wọ́n sábà ma ń sin jù gẹ́gẹ́ bí ohun ọ̀sìn jùlọ pẹ̀lú iye rẹ̀ tí tó 23.7 bílíọ́nù Àdàkọ:Ní àsìkò ọdún,[2] tí ó sì tún gbéra sọ sí bílíọ́nù mọ́kàndínlógún (19) ní ọdún 2011. Ẹyẹ adìyẹ ní ó pọ̀ jùlọ nínú ohun ọ̀sìn ilé ni gbogbo agbáyé bí ó ti jẹ́ wípé oríṣiríṣi ìgbàgbọ́ ni ẹ̀yà, ìtàn, ẹ̀sìn, èdè òun ìran orísiríṣi ní nípa sínsin adìyẹ gẹ́gẹ́ bí ohun ọ̀sìn.


Remove ads

Ìfohùnpè

Thumb
Didactic model of a chicken.

Akọ adìyẹ ni wọ́n ń pe ní cock ní èdè gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n sì ń pen rooster ní èdè Amẹ́ríkà.[3][4]

Àwọn ìfohùnpè míràn ni:

  • Wọ́n ń pe: ÒròmọdìyẹBiddy'. [5][6]
  • Wọ́n an pe akọ adìyẹ tí wọ́n ti tẹ̀ lọ́dàá ní Capon [lower-alpha 1]
  • Wọ́n ń pe adìyẹ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà ní Chick [7]
  • Wọ́n ń pe Akọ adìyẹ tí kò tìí pọ́dún kan ní Cockerel[8]
  • Wọ́n ń pe Obí dìyẹ tí ìyá àti bàbá rẹ̀ kìí ṣe ẹ̀yà kan náà ní Dunghill fowl.[9]
  • Wọ́n an pe abo adìyẹ tí kò tíì pe ọdún kan ní Pullet[10][11]
Remove ads

Bí Won ṣe rí ati ibùgbé wọn

Thumb
In most breeds the adult rooster can be distinguished from the hen by his larger comb.
Thumb
Comb of a hen.

Àwọn adìyẹ jẹ́ ẹ̀ya ẹranko jewé jeku (omnivore).[12] Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n ma ń fẹsẹ̀ walẹ̀ tàbí tànlẹ̀ láti wá hóró èso, kòkòrò gẹ́gẹ́ bí ounjẹ tó fi mo pípa àwọn eranko ilé bí alángbá ọmọ eku[13] tàbí ọmọ aṣẹ̀ṣẹ̀ pa ejò fún jíjẹ.[14] Adìyẹ ní ànfaní láti lò tó ọdún márùún sí mẹ́wá láyé, èyí tó dàgbà jùlọ gẹ́gẹ́ bí àwọn Guinness World Records.[15] ti sọ ni ó lo ọdún mẹ́rìndínlógún [16]

Remove ads

Ìyàtọ̀

Thumb
Anatomy of a chicken.
Thumb
Diagram of a chicken skull.
Thumb
Eggs from different breeds

A lè ṣe àdáyanrí akọ adìyẹ yàtọ̀ sí abo adìyẹ pẹ̀lú ìtí ìdí wọn tó ma ń pọ̀ yẹbẹ-yẹbẹ àti ìyẹ́ ọrùn wọn tó ma ń rí jọ̀bọ̀-jọ̀bọ̀ ati bí ara wọn ṣe ma ń dá yinrin yinrin ju ti obídìyẹ lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé nínú àwọn ẹ̀yà àwọn adìyẹ míràn, iyẹ́ ọrùn akọ adìyẹ nìkan ati ọrùn rẹ̀ tí ó ma ń rí sọọrọ sókè ni ó fi ma ń yàtọ̀ sí abo adìyẹ. A tún lè lo ìrísí ẹsẹ̀ àti ìganẹsẹ̀ wọn láti fi ṣe ìyàtọ̀ láàrín takọ-tabo adìyẹ tí a ń sọ yí. Bákan náà ni a lè fi ogbe orí àkùkọ da wọn mọ̀ yàtọ̀ sí abo adìyẹ. Lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn akọ adìyẹ kọ̀ọ̀kan má ń hu irun tàbí iyẹ́ ní abẹ́ ojú wọ́n látàrí àwọn oògùn ati abẹ́rẹ́ tí wọ́n bá ti fún wọn kí wọ́n lè dagbagbà yàtọ̀. [17] Àwọn adìyẹ ilé kò fi bẹ́ẹ̀ ní ànfaní láti fo lọ títí, wọ́n kò lè fò sórí ig, odi, ati inú igbó tí wọn yóò ti ní ànfaní láti jẹ̀. Wọ́n lè fò fẹ̀rẹ̀ láti gbafẹ́ nínú àdúgbò wọn tàbí kí wọ́n fò pìrìrì nígbà tí wọ́n kẹ́fin ewu kan tàbí òmíràn.

Àwọn itọ́ka sí

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads