Èdè Áfríkáánì

From Wikipedia, the free encyclopedia

Remove ads

Àdàkọ:Wiktionary Èdè ìwọ̀ oòrùn Jámìnì (a West Germany language) tí ó wáyé láti ara Dọ́ọ̀jì (Dutuh) ni eléyìí tí wọ́n ń sọ ní Gúsù Aáfíríkà. Àwọn tí ó ń sọ ọ́ tó míhíọ̀nù mẹ́fà. Wọ́n ń sọ ọ́ ní Nàmíbíà, màláwì, Zambia àti Zimbabwe. Àwọn kan tí ó sì ti ṣe àtìpó lọ sí ilẹ̀ Australia àti Canada náà ń sọ èdè náà. Wọ́n tún máa ń pa èdè yìí ni kéépú Dọọ̀jì (lapa Dutch). Èdè àwọn tí ó wá tẹ ilẹ̀ Gúsù Aáfíríkà dó ní ṣẹ́ńtúrì kẹtàdínlógún (17th century) ni ṣùgbọ́n ó ti wá yàtọ̀ sí èdè Dọ́ọ̀jì (Dutch) ti ilẹ̀ Úroòpù (Europe) báyìí nítorí èdè àdúgbò kọ̀ọ̀kan ti ń wọ inú rẹ̀. Èdè yìí ni èdè tí ó lé ní ìdajì àwọn funfun tí ó dó sí Gúsù Aáfíríkà ń sọ. Ìdá àádọ́sà n-án àwọn tí òbí wọn jẹ́ ẹ̀yà méjì ni ó sì ń sọ èdè yìí pẹ̀lú. Láti ọdún 1925 ni wọn ti ń lo èdè yìí pẹ̀lú èdè Gẹ̀ẹ́sì gẹ́gẹ́ bí èdè ìjọba. Èdè yìí tin í lítírésọ̀. Àkọtọ́ Rómáànù ni wọ́n fi ń kọ ọ́.

Quick Facts Afrikaans, Sísọ ní ...


Remove ads
Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads