Èdè Árámáìkì

From Wikipedia, the free encyclopedia

Remove ads

Èdè Árámáìkì je ara èdè Sèmítíìkì (Semitic). Àwon tí ó ń so èdè yìí tó egbèrún lónà igba ní Ìráànù (Iran) àti Ìráàkì (Iraq) pèlú òpòlopò àwon mìíràn tí wón tún ń so ó ní Ààrin gbùngbùn ìlà-òòrùn àgbáyé (Middle tast). Láti séńtúrì kefà ni wón ti ń fi Árámáìkì àtijó (Classical Aramaic) ko nnkan sílè ní Ààrin gbingbein ìlà-oòrùn àgbáyé (Middle East). Hébéérù ni ó wá gba ipò rè gégé bí èdè tí àwon júù ń so.

Quick facts Aramaic, Ìpè ...

Èka-èdè ìwò-oòrùn èdè yìí (Western dialect) ni èdè tí Jéésù Kristì àti àwon omo èyìn rè ń so. Èka-èdè kán tí ó wá láti ara èka-èdè yìí ni wón sì ń so ní àwon abúlé kan ní ilè Síríà àti Lébánóònù.

Ní nnkan bíi séńtúrì kéje ni èdè Lárúbáwá gba ipò èdè Árámáìkì. Èka-èdè apá ìwo-oòrùn èdè yìí tí a ń pè ní Síríàkì (Syricac) ni àwon ìjo Àgùdà ará fíríàkì (Syriac Catholic) ń lò.

Álúfábéètì méjìlélógún ni èdè yìí ní. Èdè yìí sì se pàtàkì nítorí pé láti ara rè ni Hébéérù, Lárúbáwá àti àwon èdè mìíràn ti dìde.


Remove ads

Itokasi

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads