Olori
From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
Olorì tí atún mò sí Aya Ọba tàbí ìyàwó ọba jé iyawo sí oba tówà ní orí oyè. Ní àwon ìlú tàbí agbègbè tí asa wón gbà ki oba fé ju iyawo kan lo, a lè pe gbogbo ìyàwó oba ní ayaba. Bí o tilẹ̀ jẹ́ wípé ayaba jé ẹni iyi ní àwùjọ, bákàn náà ni olorì ko ní agbára kankan lọ́wọ́ ara rè yàtọ̀ sí ipò tí ìlú bá yàn án sí lẹ́yìn inẹ́ ayaaba ní ilẹ̀ Yorùbá. [1]
Lílo orúkọ yí
Bí Ọba bá jẹ́ aláya púpọ̀, ìyàwó àkọ́kọ́ tí Ọba bá fẹ́ ni ó ma ń jẹ́ Olorì àgbà tí àwọn ayaaba tókù á sì ma jẹ́ Olorì tàbí ayaaba lẹ́ẹ̀dẹ Ọba. Ìyáàfin ni ipò tí èyíkéyí nínú ayaaba lè wà lẹ́yìn tí Kábíèsí bá w'àjà (ikú). Èyí ń túmọ̀ sí wípé Olorì tí ó bá dàgbà sí ààfin tí ó sì kọ̀ láti fẹ́ ẹlòmíràn lẹ́yìn ìpapòdà ọkọ rẹ̀ tí ó jẹ́ Ọba ni wọ́n ma ń wà láàfin tí wọ́n sì ma ń ran àwọn ayaaba tuntun lọ́wọ́ nípa ìtàn, ìrírí, àti àwọn nkan mìíràn kí ìṣèlú lè ma lọ lẹ́sẹẹsẹ láàfin.[2]
Remove ads
Àwọn obìnrin tí wọ́n ti jẹ́ Olorì rí
- Charlotte Obasa
- Efunroye Tinubu
- Keisha Omilana
- Kofoworola Ademola
- Mo'Cheddah
- Moremi Ajasoro
- Oronsen
- Simi
Ẹ tún wo
- Oba
Àwọn ìtọ́kasí
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads