Bọ́lá Tinúbú

Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà From Wikipedia, the free encyclopedia

Bọ́lá Tinúbú
Remove ads

Bọ́lá Ahmed Tinúbú (ọjọ́ ìbí Ọjọ́ kàndínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹ́ta, ọdun 1952) jẹ́ Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọ́n ṣe ìbúra fún lọ́jọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún ọdún 2023 lẹ́yìn tí ó jáwé olúborí nínú ìdìbò ààrẹ ọdun 2023.[1] Ó jẹ́ Gómìnà-àná Ìpínlẹ̀ Èkó láàrin ọdún 29 May odun 1999 títí di ọdún 29 May, 2007.[2] Àwọn ará ìlú ti kọ́kọ́ dìbò yàn Bola Ahmed Tinubu láti di Sẹ́nétọ̀ ní ọdún 1992, àmọ́ wọ́n fagilé ìbò náà ní ọdún (12 June, 1993)[3]

Quick facts Bola Tinubu, 12th Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó ...
Remove ads

Kíkéde ète láti dupò ààre

Ní ọjọ́ kọkànlá, oṣù kíní, ọdún 2022(January 11, 2022), Bola Ahmed kéde ète rẹ̀ láti dupò ààrẹ Nàìjíríà ní odún 2023 lábé ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress(APC).[4] Ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹfà ọdún 2022, Tinubu jáwé olúborí nínú ìdìbò-abẹ́lé ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress(APC) pẹ̀lú àmì ayò 1271, láti borí Igbákejì Ààrẹ Yẹmí Ọ̀ṣínbàjò àti Rotimi Amaechi tí ó gba 235(Osinbajo) àti 316(Rotimi).[5][6]

Remove ads

Àwọn Ìtọ́kasí

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads