Kàmbódíà

From Wikipedia, the free encyclopedia

Kàmbódíà
Remove ads

Ileoba Kambodia, to je mimo bi Kampuchea tele, Àdàkọ:Lang-km tabi Preăh Réachéa Nachâk Kâmpŭchea, to wa lati Sanskrit Kambujadesa (कम्बोजदेश)), je orile-ede ni Guusuilaorun Asia to ni bode mo Thailand ni iwoorun ati ariwaiwoorun, Laos ni ariwa, Vietnam ni ilaorun ati guusuilaorun, ati Ikun-omi Thailandi ni guusu. Jeografi ile Kambodia wa labe Odo Mekong (Khmer: Tonle Thom (ទន្លេធំ) tabi "odo ninla") ati Tonlé Sap (ទន្លេសាប; "adagun odo tutu").

Quick Facts Kingdom of Cambodia ព្រះរាជាណាចក្រកម្ពុជាPreăh Réachéa Anachâk Kâmpŭchea, Olùìlú àti ìlú tótóbijùlọ ...

Kambodia je ifobaje onilana-ibagbepo pelu Norodom Sihamoni gege bi Oba. Phnom Penh ni oluilu re ati ilu titobijulo nibe, ohun si tun ni gbanga fun okowo, aje, ile-ise ati asa ni Kambodia. Siem Reap, to je ilu to sunmo Angkor Wat ni enu bode si agbegbe Angkor nibi to je ibi ibewo. Battambang, ilu titobijulo ni apaiwoorun Kambodia, ggbajumo fun ogbin iresi re, Sihanoukville, ilu leba odo ni ebute alakoko ati ibi igbadun eti odo.

Itobi Kambodia fe to 181,035 square kilometres (69,898 sq mi) ati iye awon eniyan to ju egbegberun 14 lo ti won je Khmer. Araalu Kambodia la n pe ni "ara Kambodia" tabi "Khmer", botilejepe yi to gbeyin yi ntokasi si awon eya eniyan Khmer. Opo awon ara Kambodia ni won je elesin Theravada Buddhist, sugbon bakanna ni awon elesin musulumi Cham tun wa nibe, bakanna awon ni awaon eya Saina, Vietnam ati awon eya elesin oosa tun wa.[4].

Ise-Agbe ni eyi to se kokojulo ninu okowo Kambodia, pelu bi 59% awon eniyan ngbera le ise agbe fun igbe won (nibi ti iresi ti je ogbin pataki).[5] Aso, isebewo, ati ile kiko na tun se pataki, ibewo awon ara okere si Angkor Wat fe to egbegberun 4.[6] Ni 2005, alumomi ile bi epo ati efuufu adanida je wiwari ni labe agbegbe omi Kambodia, nigbati wiwajade won fun tita ba bere ni 2011, ipawo epo yi yio kopa gidigidi lori okowo ile Kambodia.[7]


Remove ads

Itokasi

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads