Ìpínlẹ̀ Kaduna
Ìkan lára àwọn ìpínlẹ̀ ní orílé-èdè Nàìjíríà From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
Ìpínlẹ̀ Kàdúná jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn Ìpínlẹ̀ mẹ́rìdínlógójì ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìpínlẹ̀ Kàdúná jẹ́ ọkan lára ìpínlẹ̀ tó wà ní apá Àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Olú-ìlú ìpínlẹ̀ yìí ń bá a jórúkọ, ìlú Kàdúná, èyí tí ó jẹ́ ìlú kẹ́jọ tí ó tóbi jù ní orílẹ̀-èdè yìí ní ọdún 2006. Wọ́n dá ìpínlẹ̀ yìí sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ìpínlẹ̀ àárín-gbùngbùn Àríwá ní ọdún 1967, èyí tí ó yíká Ìpínlẹ̀ Katsina òde-òní. Ní ọdún 1987 ní Ìpínlẹ̀ Kàdúná ṣẹ ààlà-ọ̀nà wọn. Ìnagijẹ Kàdúná ní Center of learnig (Ilé fún ẹ̀kọ́). Orúkọ yìí ṣe rẹ́gí wọn Nítorí ọ̀pọ̀ ilé-ẹ̀kọ́ tó ní kìmí ni ó wà ní ìpínlẹ̀ náà, àpẹẹrẹ ní Ahmadu Bello University.[2]
Ìpínlẹ̀ Kàdúná òde-òní jẹ́ ilé ìṣura fún àwọn ohun ìlàjú ilẹ̀ Áfíríkà, kódà, Nok civilization tí ó gbèrú láti c.1500 BC sí c. 500 AD náà wà ní bẹ̀.[3][4] Ní séntúrì 9th, òwúlẹ̀-wútàn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ya'qubi ṣe àkọsílẹ̀ ìwàláyé Ìjọba Hausa, èyí tí ó wà kí wón tó sọ ọ́ di Sokoto Caliphate ní ọdún 1800 lẹ́yìn ìjà àwọn Fulani.[5] Ní àkókò ìmúnisìn, àwọn olùdarí ilẹ̀- Britain sọ Kàdúná di olú-ìlú Àbọ̀ ní Àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
![]() |
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Remove ads
Itokasi
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads