Olè
From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
Olè jẹ́ ọ̀nà kan tí a ń gbà láti jí ohun ìní elòmíràn, láì gba ìyànda láti ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú èrò láti fi ohun ìní rẹ̀ ọ̀hún dùn ún[1][2][3]. Olè pín sí oríṣirìṣi ọ̀nà bíi : Ìdigunjalè, ìwà ajẹ̀bánu, ìlọ́nilọ́wọ́-gbà àti gbígba ẹrù olè sákàtà eni. [2] Ní ilẹ̀ Yorùbá, oríṣiríṣi orúkọ ni wọ́n ma ń pe olè, lára rẹ̀ ni: ''gbéwiri'', ''jàgùdà'', ''àlọ́ kólóhun-kígbe'', ''fìrí'ńdí-ọ̀kẹ́'', ''ọ̀fán àn'', àti bẹ́ẹ̀

bẹ́ẹ̀ lọ.
Remove ads
Ohun tí ó ń fa olè jíjà

Èrò tàbí ohun tí ó fa jíja olè pọ̀ lóriṣiríṣi, ó lè jẹ́ ìgbé-ayé tí kò rọgbọ látàrí ọrọ̀-ajé àwùjọ tó dẹnu kọlẹ̀ tàbí kí ó jẹ́ ìwà tàbí ìṣesì ẹni bíi : ''ìránró, ìbínú, ìbànújẹ́, ẹ̀dùn-ọkàn, ìbẹ̀rù, ìjẹni nípá, ìrẹ̀wẹ̀sì, wíwá agbára. O sì tún lè jẹ́ kíkẹ́gbẹ́ tí kò dára àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. [4].
Àwon ìtọ́kasí
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads