Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́

Olóṣèlú From Wikipedia, the free encyclopedia

Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́
Remove ads

Matthew Àrẹ̀mú Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ GCFR[1] (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ karùn-ún oṣù kẹta ọdún 1937) jẹ́ gbajúmọ̀ àgbà olóṣèlú, ajagun-fẹ̀yíntí àti Ààrẹ àná orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Orúkọ bàbá rẹ̀ ni Amos Àdìgún Ọbalúayésanjọ́ "Obasanjo" Bánkọ́lé, ìyá rẹ̀ sìn ń jẹ́ Àṣàbí.Ọbásanjọ́ jẹ́ ọmọ bíbí Òwu ní ìlú Abẹ́òkúta ní ìpínlẹ̀ Ògùn lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ìyá rẹ̀ kú ní ọdún 1958, bàbá rẹ̀ sìn kú bákan náà ní ọdún 1959.

Quick facts Olusegun Obasanjo, Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà 12k ...
Remove ads

Ìgbà èwe rẹ̀

Wọn bi Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ ni Ojo Kaarun, Oṣù Kẹta, ọdun mẹtadinlojilẹdẹgbẹwa (1937) fún Amos Obaluayesanjo Bankole ati Asabi lilu Ìbògùn Ọláogun. O jẹ akọbi awọ̀n obi re, wọn bi ọmọ mẹjọ tẹle, ṣugbon arabirin kan loni ti ò kù. O di omo orukan nigba ti o pe omodun mejilelogun. Ile iwe Saint David Ebenezer School ni Ibogun ni oloye obasanjo ti ka iwa alakobere( primary school education),ni odun 1948. Oloye Obasanjo jé ògágun tó tifèyìntì kúrò nínú iṣẹ́ Ológun ilè Nàìjíríà ati olóṣèlú ọmọ ilè Naijiria. Oun ni Ààre ilè Naijiria lati odún 1999 títí dé ọdún 2007. Èyí ni ìgbà iketa tí Obasanjo yíò jé Ààre orílè-èdè Nàìjírìa. O ti koko je Aare laye Igba ijoba ologun laarin odun 19761979.[2][3]

Remove ads

Ìfẹ̀yìntì rẹ̀

Thumb
Obasanjo ní ọdún 1978

Lẹ́yìn tí ó fẹ̀yìntì, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àdáṣe tirẹ̀, ìyẹn ní iṣẹ́ àgbẹ̀. Ilé-iṣẹ́ àgbẹ̀ rẹ̀, (Obasanjo Farms) gbòòrò; tó fẹ́rẹ ma sí abala iṣé àgbẹ̀ tí kò sí níbẹ̀. Láàrín ọdún 1976 sí 1999, Obasanjo di ẹni mímọ̀ ní gbogbo àgbáyé. Akinkanju ni ninu eto oselu agbaye. O wa ninu awon Igbimo to n petu si aawo ni awon orile-ede to n jagun, paapaa ni ile adulawo. O je ogunna gbongbo ninu egbe kan to koriira iwa ibaje, iyen ni Transparency International. Ni odun 1999, Obasanjo tun di Aare alagbada fun orile-ede Naijiria, labe asia egbe PDP. A tun fi ibo yan an pada gege bi Aare lekeji ni 2003..[4] Okan pataki ninu awon afojusun ijoba Obasanjo ni igbogun ti iwa jegudujera (Anti-Corruption). Obasanjo gbiyanju dida ogo Naijiria pada laarin awon akegbe re ni agbaye (Committee of nations). O tun iyi owo naira to ti di aburunmu bi omi gaari se, gbigbowo-lori-oja (inflation) si dinku jojo. Iye owo afipamo-soke-okun (external reserves) Naijiria ti ga gan-an ni, o to $40 billion bayii. Obasanjo tun fidi awon banki wa mule gbogbo, pipo ti won po yanturu tele ti dinku, won o ju meeedogbon lo mo bayii. Eyi mu ki awon eniyan ni igbekele ninu fifi owo pamo si banki, won si tun le ya owo fun idagbasoke okowo won gbogbo. Lara awon eto ti ijoba Obasanjo n se ni tita awon ogun ijoba fun awon aladani (privatisation policy). Eto yii ku die kaato. Idi ni pe awon olowo lo le ra awon ogun bee, talika kankan ko le ra won.

Ni Oṣu Kẹjọ ọdun 2021, Ẹgbẹ Afirika yan Olusegun Obasanjo gẹgẹbi Aṣoju giga fun Alaafia ni Iwo Afirika.


Thumb

Remove ads

Àwọn ìtọ́kasí

Àwọn àjápọ̀ látìta

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads