Sánmọ̀

From Wikipedia, the free encyclopedia

Sánmọ̀
Remove ads

Sánmọ̀ tabí Ojú Ọ̀run jẹ́ gbogbo ohun tí ó wà lókè Ilẹ̀ níbi tí ohun bí Kùrukùru, Oòrùn, Òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ ti ń yọjú wo ilẹ̀ lásìkò ìkọ̀ọ̀kan wọn. Ní inú ìmọ̀ ojú-ọ̀run, sánmọ̀ yí ni wọ́n ń pè ní ahòho, níbi tí oòrun, òṣùpá, àti àwọn ìràwọ̀ ti dàbí ẹni wípé wọ́n ń rọ̀ kiriká ọ̀run fúra rẹ̀,ní ọ̀gangan ilẹ̀.

Thumb
The sky above the clouds

Ọ̀nà tí sánmọ̀ pín sí

Sánmọ̀ tàbí ojú-_ọ̀run yí náà pín sí ọ̀nà méjì. Àkọ́kọ́ ni kùrukùru, èyí jẹ́ ìpele akọ́kọ́ àti ohun tí ó bo ojú-ọ̀run gan an fúra rẹ̀. Èkejì ni ahòho ọ̀run, ní i tí àwọn ìràwọ̀,Oòrùn , ati Òṣùpá ti ń yọjú lásìkò wọn gbogbo.[1] Lọ́pọ̀ ìgbà, kùrukùru ojú sánmọ̀ ni ó súnmọ́ ilẹ̀ jùlọ tí ó jẹ́ wípé bí a bá gbójú sókè, oun ni akọ́kọ́ máa rí.

Àwọn àríwòye sánmọ̀

Ní ojú mọmọ tàbí ní àsìkò ọ̀sán, ojú sánmọ̀ sába ma ń ní àwọ̀ búlúù tàbí yẹ́lò tí Oòrùn yóò sì tàn kálẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ tí a kò fi ní nílò iná tabí ihun kan mìíràn tí a lè fi òye rẹ̀ ríran ju òye ọjọ́ lọ. Bí ó ti di àṣálẹ́, sánmọ̀ yóò dúdú kẹlẹ kẹlẹ, ní èyí tí ilẹ̀ náà yóò dúdú pẹ̀lú nítorí ìmọ́lẹ̀ sánmọ̀ ni ìmọ́lẹ̀ ilẹ̀. Ní àsìkò yí, gbogbo ohun alàyé pátá ni wọn yóò nílò ohun tí ó lè jẹ́ gẹ́gẹ́ bí òye tàbí iná tí yóò ms fi wọ́n mọ̀nà. Àwọn àsìkò yí ni òṣùpá ati àwọn ìràwọ̀ yóò yọ tí wọn yóò sì tànmọ́lẹ̀ sí orí ilẹ̀.[2][3][4][5].

Remove ads

Àwọn Ìtọ́kasí

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads