Ìlèdí
From Wikipedia, the free encyclopedia
Ìlèdí fún ọmọdé, ìlèdí tàbí ìlàpọ̀n fún àgbà tàbí páàdì fún àwọn obìnrin jẹ́ ohun èlò kan tí ó ma ń gba omi bíi ìtọ̀ àti Ìgbẹ́ Ènìyàn dúró lára ọmọ ìkókó tàbí ọmọdé. Ó tún jẹ́ ohun èlò tí àwọn obìnrin ma ń lò láti fi gba ẹ̀jẹ̀ dúró lásìkò tí wọ́n bá ń ṣe nkan oṣù, tàbí tí wọ́n bá bímọ, bẹ́ẹ̀ wọ́n ma ń lòó láti fi fí ojú ara àwọn obìnrin tí wọ́n bá ṣiṣẹ́ abẹ fún. Ó ṣe pàtàkì kí wọ́n ma pàrọ̀ ìlèdí ní àìmọye ìgbà nínú ọjọ́ kan, ìyẹn bí nkan oṣù náà bá ṣe pọ̀ sí. Wọ́n ma ń ṣe ìlèdí látara àwọn ohun èlò oríṣiríṣi, ìyẹ̀n bí wọ́n bá ṣe fẹ́ kó rí.