From Wikipedia, the free encyclopedia
Ẹ̀wà ni ìkan lára àwọn igi eléso tí ó ń so ohun jíjẹ ẹlẹ́yọ, tí ènìyàn tàbí ẹranko lè jẹ gẹ́gẹ́ bí óúnjẹ. [1]
Ọ̀nà tí a lè gbà láti sè tàbí jẹ ẹ̀wà pọ̀ jántì-rẹrẹ. Lára rẹ̀ ni:
Yàtọ̀ sí àwọn óuńjẹ akẹgbẹ́ ẹ̀wà tókù, ẹ̀wà ní tirẹ̀ jẹ́ ohun eléso tí ó nílò ooru tàbí oòrun gbígbóná láti dàgbà. Kí ẹ̀wà tó lè dàgbà débi tí yóò tó kórè, yóò lò tó ọjọ́ Márùndínlọ́gọ́ta sí ọgọ́ta ọjọ́ kí ó tó lè ṣe é kórè lóko. [3] Níbẹ̀rẹ̀ ìdàgbàsókè rẹ̀, èpo tàbi pádi rẹ̀ yóò wà ní àwọ̀ ewé mìnìjọ̀, nígbá tí ó bá tún ìdàgbàsókè díẹ̀ si, pádi rẹ̀ yóò di àwọ̀ pípọ́n rẹ́súrẹ́sú, nígbà tí àwọ rẹ̀ yóò di dúdú nígbà tí ó bá gbó tán. Púpọ̀ ẹ̀wà ni ó ma ń nílò ìrànlọ́wọ́ igi lnítòsí wọn láti fi gbéra sókè, àmọ́, ẹ̀wà ṣèsé kìí nílò ìrànwọ́ kankan láti fi dàgbà rárá.[4] [5]
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Every time you click a link to Wikipedia, Wiktionary or Wikiquote in your browser's search results, it will show the modern Wikiwand interface.
Wikiwand extension is a five stars, simple, with minimum permission required to keep your browsing private, safe and transparent.