Àkàrà

Ẹ̀wà tí a bó, tí a sì yí róbóróbó, tí a wá dín nínú epo tàbí òróró From Wikipedia, the free encyclopedia

Àkàrà
Remove ads

Àkàrà jẹ́ oúnjẹ abínibí ìbílẹ̀ ilẹ̀ Yorùbá àti púpọ̀ nínú ilẹ̀ Adúláwọ̀.

Quick facts Alternative names, Course ...
Remove ads

Ṣíṣe àkàrà

Àkàrà wà nínú àrà tí wọ́n ma ń fi ẹ̀wà dá. Wọ́n ma ń rẹ ẹ̀wà sínú omi, fún bii ọgbọ̀n ìṣẹ́jú tàbí wákàtí kan kí ó lè rọ̀. Lẹ́yìn èyí, wọn yóò fi ata, àlùbọ́sà, edé àti àwọn nkan mìíràn tí ó bá wù wá si kí wọ́n tó lọ̀ọ́ kúná. Lẹ́yìn tí wọ́n bá lọ̀ọ́ tán, wọn yóò gbé epo tàbí òróró kaná tí wọn yóò sì ma dá ẹ̀wà náà sínú epo yí kí ó lè dín.[1][2]

Bí wọ́n ṣe ń jẹ àkàrà

Wọ́n lè jẹ àkàrà lásán, wọ́n lè fi jẹ̀kọ, jẹ búrẹ́dì, mùkọ, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[3]

Ṣíṣaara lóore

Akara ní àwọn èròjà láti múni sanra, torí àwọn èròjà proteins, vitamins àti minerals bí i calcium, iron àti zinc inú rẹ̀.[4][5] Àmọ́ ṣáá, àwọn èròjà inú rẹ̀ lè ti dínkù nítorí àwọn àfikún kan bí iphytates, fibers, lectins, polyphenols àti tannins tí kì í ṣe ara lóore.[4]

Àwọn Ìtọ́kasí

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads