Jos Plateau jẹ́ ilẹ̀ òkè kan tí ó sún mọ́ àárín orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Wọ́n fún ilẹ̀ náà ní orúkọ rẹ̀ nítorí pé ó wà ní Ìpínlẹ̀ Plateau, àti nítorí Jos, olú-ìlú ìpínlẹ̀ Plateau. Ilẹ̀ òkè náà jẹ́ ilé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn pẹ̀lú oríṣi àṣà àti èdè.

Thumb
Àwòrán máàpù ilẹ̀ Jos

Ilẹ̀ Jos Plateau

Jos Plateau ní ilẹ̀ tí ó tó 8600 km². Gígún rẹ̀ kọjá òkun sì tó kìlómítà kan, òun ni ó tóbi jù nínú àwọn ilẹ̀ tí ó fi kìlómítà kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ kọjá òkun ni Nàìjíríà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ odò ní orísun wọn láti Jos plateau. Àwọn odò bi Odò Kaduna, Odò Gongola.

Àwọn ènìyàn tí ó ń gbé ibẹ̀

Jos Plateau súnmọ́ àárín Nàìjíríà, ó sì tó àwọn oríṣiríṣi ẹ̀yà ọgọ́ta tí ó ń gbé ní ilẹ̀ [1] Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èdè tí wọ́n ń sọ níbẹ̀ jẹ́ àwọn èdè tí ó jọ mọ́ èdè Chad.[2] Méjì nínú àwọn èdè tí wọ́n ń sọ jù níbẹ̀ ni èdè Berom àti èdè Ngas. Àwọn èdè míràn ni Mwaghavul, Pyem, Ron, Afizere, Anaguta, Aten, Irigwe, Chokfem, Kofyar, Kulere, Miship, Mupun àti Montol.

Àwọn Ìtọ́kasí

Wikiwand in your browser!

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Every time you click a link to Wikipedia, Wiktionary or Wikiquote in your browser's search results, it will show the modern Wikiwand interface.

Wikiwand extension is a five stars, simple, with minimum permission required to keep your browsing private, safe and transparent.