Ẹ̀wà

From Wikipedia, the free encyclopedia

Ẹ̀wà
Remove ads

Ẹ̀wà ni ìkan lára àwọn igi eléso tí ó ń so ohun jíjẹ ẹlẹ́yọ, tí ènìyàn tàbí ẹranko lè jẹ gẹ́gẹ́ bí óúnjẹ. [1]

Thumb
Ẹ̀wà
Thumb
"Painted Pony" dry bean (Phaseolus vulgaris)
Thumb
Bean plant
Thumb
Beans and plantain

Oríṣi Ọ̀nà tí a lè gbà jẹ ẹ̀wà

Ọ̀nà tí a lè gbà láti sè tàbí jẹ ẹ̀wà pọ̀ jántì-rẹrẹ. Lára rẹ̀ ni:

  1. Sísè lásán
  2. Sísèé pẹ̀lú àwọn ohun jíjẹ mìíràn bí Iṣu, àgbàdo, ìrẹsì, kókò, ọ̀gẹ̀dẹ̀ yálà díndín tàbí bíbọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
  3. A lè fi ẹ̀wà ṣe mọ́ímọ́í àti àkàrà àti ọ̀nà mìíràn tí kálukú bá tún mọ̀ tí wọn lè lòó sí.
  4. A lè fi ẹ̀wà se ọbẹ̀ ìbílẹ̀ tí a ń pè ní gbẹ̀gìrì [2]

Gbígbìn àti kíkórè ẹ̀wà

Thumb
Field beans (broad beans, Vicia faba), ready for harvest

Yàtọ̀ sí àwọn óuńjẹ akẹgbẹ́ ẹ̀wà tókù, ẹ̀wà ní tirẹ̀ jẹ́ ohun eléso tí ó nílò ooru tàbí oòrun gbígbóná láti dàgbà. Kí ẹ̀wà tó lè dàgbà débi tí yóò tó kórè, yóò lò tó ọjọ́ Márùndínlọ́gọ́ta sí ọgọ́ta ọjọ́ kí ó tó lè ṣe é kórè lóko. [3] Níbẹ̀rẹ̀ ìdàgbàsókè rẹ̀, èpo tàbi pádi rẹ̀ yóò wà ní àwọ̀ ewé mìnìjọ̀, nígbá tí ó bá tún ìdàgbàsókè díẹ̀ si, pádi rẹ̀ yóò di àwọ̀ pípọ́n rẹ́súrẹ́sú, nígbà tí àwọ rẹ̀ yóò di dúdú nígbà tí ó bá gbó tán. Púpọ̀ ẹ̀wà ni ó ma ń nílò ìrànlọ́wọ́ igi lnítòsí wọn láti fi gbéra sókè, àmọ́, ẹ̀wà ṣèsé kìí nílò ìrànwọ́ kankan láti fi dàgbà rárá.[4] [5]

Thumb
Bean creeper




Remove ads

Àwọn ítọ́kasí

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads