Ọwọ́

From Wikipedia, the free encyclopedia

Ọwọ́
Remove ads

Ọwọ́ ni a lè pè ní ẹ̀ya ara tí fi ń di nkan mú tí ó si ni ọmọ-ìka púpọ̀ ní ìparí rẹ̀, òun ni ó sì kẹ́yìn ọrùn ọwọ́. A lè ṣalábàá-pàdé ọwọ́ lára àwọn ẹranko elégungun bíi: Ènìyàn, Ọ̀bọ Ìnàkí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[1] Ọwọ́ ènìyàn sábà máa ń ní ìka mẹ́rin tí àtànpàkò sì ṣ'ìkarùn ún wọn. [2][3] Àpapọ̀ gbogbo àwọn ọmọ ìka yí ni a ń pè ní ọwọ́.[2][4][5] Ọwọ́ tí a ń sọ yí ní egungun mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n(ọwọ́ kan), ọwọ́ méjéjì lápapò ní egungun mẹ́rìnléláàdọ́ta [6], èyí tí kò sí egungun sesamoid , èyí tí kìí jẹ́ iye kan náà lára ènìyàn kan sí ìkejì. Egungun mẹ́rìnlá nínú àwọn egungun ọwọ́ jẹ́ àkójọ egungun ìka pẹ̀lú àtànpàkò. Àwọn egungun àtẹ́lẹwọ́ (metacarpals) ni ó di egungun ìka pẹ̀lú egungun ọrùn ọwọ́ mú. Ọwọ́ ènìyàn kan a máa ní egungun àtẹ́lẹwọ́ márùn-ún pẹ̀lú egungun ọrùn ọwọ́ mẹ́jọ.

Quick Facts Details, Vein ...

Ọwọ́ kọ́ ipa pàtàkì lára ènìyàn ní ṣíṣe itọ́ka sí àti àpèjúwèé aláìlo gbólóhùn. Bákannáà, a máa ń lo ọmọ ìka mẹ́wẹẹ̀wá pẹ̀lu àwọn egungun ọmọ ìka làti ṣe ohunkà àti fún ìṣirò.

Remove ads

Àgbékalẹ̀

Pùpọ̀ nínú àwọn ẹranko onírunlára àti àwọn ẹranko míràn ní ẹ̀ya ara tí wọ́n fi ń di nkan mú, ṣùgbọ́n ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ kò kà wọ́n kún ọwọ́. Ọwọ́ ni a lè rí lára ipín àwọn ẹranko tí ó jọ ọ̀bọ àti ìnànkí. Kí a tó lè ka ẹ̀ya ara kún ọwọ́, ó gbọdọ̀ ní àtànpàkò tí ó dojúkọ àwọn ìka mẹ́rin míràn.


Àwọn ìtọ́kasí

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads