9ice
Olorin Naijiria From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
9ice, tí orúkọ rẹ jẹ Alexander Ábọ̀lọrẹ Adégbọlá Àkàndé (wọ́n bí ni ọjọ́ kẹtàdínlógún Oṣù Ṣéẹ́rẹ́, ọdun 1980), ó jẹ́ olórin, òǹkọ̀tàn-orin, oníjó ọmọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà. Ó gbajúmọ̀ fún ìgbédègbẹyọ̀ rẹ̀, òwe lílò àti àgbékalẹ̀ orin rẹ̀ lọ́nà àrà.

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀
Ìdílé olórogún ni 9ice ti wá, bàbá rẹ̀ ní ìyàwó márùn-ún àti ọmọ mẹ́sàn-àn ní Ìlú Ògbómọ̀ṣọ́, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní Ìwọ̀-oòrùn Nàìjíríà. Ó dàgbà ní agbègbè Shomolu Bàrígà, Èkó. Ó wù 9ice láti jẹ́ olórin. Àwọn òbí rẹ̀ ṣe àkíyèsí ẹ̀bùn orin kíkọ rẹ̀, wọ́n sì gbà á láàyè láti di olórin.[1] Ó ni ìyàwó tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Adẹ́tọ́lá Anífálájé, Ọlọ́run sì fi ọmọ jíìkí wọn.
Ní odun 2014, 9ice du ipò lábẹ́ Àsìá All Progressive Congress(APC) láti di aṣojú-ṣofin nílé Ìgbìmọ̀ Aṣofin ṣùgbọ́n kò wọlẹ́ ìbò. Nínú ìdìbò inú-ilé (Primaries) ló ti jákulẹ̀.Gómìnà Abíọ́lá Ajímọ̀bi sì fi jẹ oludàmọ́ràn pàtàkì sí gómìnà.
Remove ads
Ìdàgbàsókè
9ice lọ sí ilé-ẹ̀kọalákọ̀bẹ́ẹ̀rẹ̀ ẹ Abúlé Okuta àti Ilé-ẹ̀kọ́ Gírámà CMS. Kò kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin tí ó lọ ṣe ní Yunifásítì Ìpínlẹ̀ Èkó, ní ṣe ló gbájúmọ́ iṣẹ́ orin tí ó yàn láàyò. Ó bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ ni ọdún 2000, ó fẹ́ràn Pasuma Wonder. Kẹ́sẹ́ tí ó ń gùn ún láti fi gbe orin rẹ̀ kalẹ̀ ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àdúgbò rẹ̀ àti àwọn olórin aṣáájú tí rí ó rí bí àwókọ́ṣe bíi Ebenezer Obey, King Sunny Adé, Àlàmú Alamu, olóògbé Àyìnlá Ọmọwúra, ati ològbé Haruna Ishola.
Remove ads
Ìbẹrẹ Iṣẹ
Ní ọdún 1996, ló kọ́kọ́ ṣe rẹ́kọ̀ọ̀dù alápèjúwe tí ó pè ní Risi de Alagbaja ṣùgbọ́n ọdún 2000 ló tó gbé rẹ́kọ̀ọ̀dù àkọ́kọ́ rẹ tí ó pè ni Little Money jáde.[2][3]
Ní ọdún 2008, 9ice gbé orin Gọngọ Ásọ. Tí orin náà sí gbalẹ̀ káàkiri, èyí sì mú kí wọ́n sọ pé kí ó wà kọ orin níbi ọjọ́ọ̀bí àádọ́rùn-ún ọdún Nelson Mandela ní ìlú London, United Kingdom ní Oṣù Òkudù 2008. Ó gba àmì ẹ̀yẹ olórin tàkasúfèé tí ó dára jù lọ ní MTV Africa Music Awards.[4] He went on to win the Best Hip Hop Artist of the Year at the MTV Africa Music Awards.[5][6]
Gọngọ Aṣọ náà gbà àmì ẹ̀yẹ mẹ́rin níbi 2009 Hiphop World Awards tí ó wáyé ní International Conference Centre, Abuja.[7]
Ní ọdún 2020, 9ice gbé àwo orin mìíràn jáde ti ó pè ní "Tip of the Iceberg". Òun ni olùdásílẹ̀ àti alákòóso iléeṣẹ́ agbórin-jáde Alápòméjì Ancestral Record.[8][9]
Àrà rẹ̀
9ice máa ń lo èdè Yorùbá nínú àwọn orin é. Nígbà mìíràn ó má ń lo àwọn Òwe èdè Yorùbá, tàbí kí ó ṣe àmúlùmúlà pẹ̀lú èdè Hausa, Igbo tabi èdè òyìnbó.
Àtòjọ àwọn orin rẹ̀
- Certificate (2007)
- Gongo Aso (2008)
- Tradition (2009)
- Certificate and Tradition Reloaded (2010)
- Versus/Bashorun Gaa (2011)
- GRA/CNN (2014)
- Id Cabasa (2016)
- G.O.A.T (2018)/Classic 50 Songs (2019)
- Fear of God (2020)[10] Seku Seye (2020)
- Tip of the Iceberg: Episode 1 (2020)[11]
- Tip of the Iceberg: Episode II (2022)[12]
- Tip Of the iceberg III (2022)
- Lord Of Ajasa (2023)
- Observatory (2024)
Àwọn àmì-ẹ̀yẹ
- Nigeria Entertainment Awards Most Indigenous Act 2007
- MOBO Best African Act 2008[13]
- MTV Africa Music Awards Best Hip Hop Artist 2008[14]
- Dynamix Awards Artist of the Year 2008
- Hip Hop Awards Best Vocal Performance 2008
- Hip Awards Revelation of the Year 2008
- Hip Hop Awards Song of the Year 2009
- Hip Hop Awards Best R&B/Pop 2009
- Hip Hop Awards Album of the Year 2009
- Hip Hop Awards Artist of the Year 2009[15]
Remove ads
Ìtọ́kasí
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads