Adebáyò Faleti

Òṣéré orí ìtàgé,Akéwì ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà From Wikipedia, the free encyclopedia

Remove ads

Adébáyọ̀ Àkàndé Fálétí (wọ́n bí i ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá 1930) jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Akéwì , Olùkọ̀tàn, àti eléré orí-Ìtàgé, bákan náà ni ó tún jẹ́ oǹgbufọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì sí èdè Yorùbá, ó sì tún jẹ́ oníròyìn orí ẹ̀rọ asọ̀rọ̀-má-gbèsì Radio, Olóòtú ètò orí ẹ̀rọ agbóhùngbójìjí TV, àti Olùdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ ẹ̀rọ agbóhùngbójìjí àkọ́kọ́ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ Afíríkà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Western Nigeria Television (WNTV). [1][2]

Adebáyò Faleti
Quick Facts Adebayo Faleti, Ọjọ́ìbí ...
Remove ads

Iṣẹ́ tó yàn láàyò

Faleti tí kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ fíìmù tí ó sì tún ṣàgbéjáde wọn pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ sì ni ó kópa nínú àwọn fíìmù náà.[3] Bákan náà, ó gbajúmọ̀ fún àwọn ewì rẹ̀. Òun ni olùkọ́ àkọ́kọ́ ní Ife Odan, tó wà nítòsí ìlú EjigboÌpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.[4] Ó fìgbà kan jẹ́ Alákòóso Àgbà ní Broadcasting Corporation of Oyo State (BCOS), èyí tí ó tún ń jẹ́ Radio OYO, Ibadan.[4] Ní ọdún 1959, ó ṣiṣ́ẹ ní Western Nigerian Television (WNTV), èyí tí ó ti wá di NTA Ibadan, gẹ́gẹ́ bí i olùdarí fíìmù àti alákòóso yàrá ìyáwèé-kàwé.[4]

Remove ads

Àwọn iṣẹ́ rẹ̀

Faleti ti kópa nínú eré orí-ìtàgé pẹ̀lú fíìmù àgbéléwò, bẹ́ẹ̀ sì ní ó ti kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ fíìmù tí ó sì tún ṣàgbéjáde wọn pẹ̀lú, lára àwọn fíìmù bẹ́ẹ̀ ni: Thunderbolt: Magun (2001), Afonja (1 & 2) (2002), Basorun Gaa (2004), àti Sawo-Sogberi (2005).[5][6]

Adébáyọ̀ Fálétí náà ló ṣe ògbufọ̀ orin àmúyẹ orílẹ́-èdè Nigeria National Anthem láti èdè Gẹ̀ẹ́sì sí èdè abínibí Yorùbá. Bákan náà ni ó ṣe iṣẹ́ oǹgbufọ̀ fún Ààrẹ orílẹ́-èdè Nàìjíríà nígbà kan rí lásìkò ìṣèjọba àwọn ológun, ìyẹn Ibrahim Babangida bẹ́ẹ̀ ni fún ẹni tí ó ti fi ìgbà kan jẹ́ Ààrẹ-fìdíhẹ Chief Ernest Shonekan nígbà ìṣèjọba àwọn ológun, nípa lílo èdè Yorùbá tó gbámúṣé. Fálétí ti tẹ Ìwé-Atúmọ èdè Dictionary Yorùbá ní èyí tí ó ní àbùdá ògidì Yorùbá nínú. Adébáyọ̀ Fálétí ti gba onírúurú àmì-ẹ̀yẹ ìdánilọ́lá oríṣiríṣi nílẹ̀ yìí àti lókè Òkun pẹ̀lú. [7] [8]

Remove ads

Ọ̀kan lára àwọn ewì rẹ̀

Obìin mẹ́ìndínlógún

N ní ń bẹ́ lọ́ọ̀dẹ̀ẹ Ṣàngó

Ńbi ká sánpá

Ńbi ká yan

LỌyá fi gbọkọ lọ́wọ́ọ gbogbo wọn 5

Ńbii ká sọ̀rọ̀, ká fa kòmóòkun yọ

N la ṣe ń perúu yín léléwì pàtàkì

Fohùn òkè ta ko tìsàlẹ̀ nìkan

Kọ́ là ń pè léwì

Yàtọ̀ sáfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ àti tààrà 10

Òwe tún ń bẹ rẹrẹrẹ

Wọn a sọ̀rọ̀ tó gbayì létè

Wọn a fi wíwúni lórí lé e

Èyún-ùn nìkan kọ́, kò sẹ́ni tí ò mọ̀yún-ùn

Àní níbii ká máṣà ìṣẹ̀nbáyé 15

Kí gbogbo rẹ̀ tún kú dùn-ún-ùn bí ojú afọ́jú

N la ṣe ń peruu wọn ní baba

Ẹni tó mọ̀Bàdàn tán tó tún mọ Láyípo pẹ̀lú ẹ̀

Tó gbégùn tó gbọ́ wọ́yọ̀wọ́yọ̀

Iwájú lọ̀pá ẹ̀bìtì ó kúkú máá ré sí 20

A kò ní í sàìmáa rí yín bá

Àwọn ìwé rẹ̀

  • Basorun Gaa
  • Adebayo Faleti (1985) Ogun Àwítélè Ibadan; University Press Limited, ISBN 0-19-575073-X Ojú-iwé 48.
  • Adebayo Faleti (1993) Omo Olókùn Esin Heinemann Educational Books (Nigeria) PLC. ISBN 978-129-231-8

Àwọn Ìtọ́kasí

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads