Ìpínlẹ̀ Abia

Ìkan lára àwọn ìpínlẹ̀ ní orílé-èdè Nàìjíríà From Wikipedia, the free encyclopedia

Ìpínlẹ̀ Abia
Remove ads


Ìpínlẹ̀ Abia (Igbo: Ȯha Abia) jẹ́ ìpínlẹ̀ kan ní agbègbè gúúsù-ìlà-oòrùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, tí ó pín ààlà sí àríwá àti àríwá-ìlà-oòrùn pẹ̀lú àwọn Ìpínlẹ̀ Enugu, àti Ebonyi, Imo State sí ìwọ̀-oòrùn, ìpínlẹ̀ Cross River sí ìlà-oòrùn, ìpínlẹ̀ Akwa Ibom sí gúúsù-ìlà-oòrùn, àti ní ìpínlẹ̀ Rivers sí gúúsù. Tí wọ́n sọ lórúkọ látara ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ orúkọ àwọn agbègbè mẹ́rin tí ó pọ̀ jùlọ ní ìpínlẹ̀ náà: Aba, Bende, Isuikwuato, àti Arochukwu.[3] Olú-ìlú rẹ̀ ni Umuahia tí agbégbè tí ó gbòòrò jùlọ tí ó sì lajú jẹ́ Aba.[4]

Quick Facts Orile-ede, Oluilu ...

Ìpínlẹ̀ Abia jẹ́ ìpínlẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejìlélọ́gbọ̀n tí ó gbòòrò jùlọ ní ààyè tàbí agbègbè àti ẹlẹ́ẹ̀kẹtàdínlọ́gbọ̀n ní iye pẹ̀lú ènìyàn tí ó tó mílíọ́nnù mẹ́rindínlọ́gọ́rùn-ún-lọ́nà-igbalélọ́gọ́rin gẹ́gẹ́ bí àbájáde ọdún 2016.[5]

Lóde-òní àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Abia láti bí ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn kúnfún àwọn oríṣiríṣi ẹ̀yà, ṣùgbọ́n àwọn Igbo ni wọ́n gbilẹ̀ jù nínú àwọn olùgbé yìí.

Ní ti ètò ọrọ̀-ajé, iṣẹ́ wíwa epo àti ohun àlùmọ́nì gáààsì ni ó jẹ́ gbòóógì ní ìpínlẹ̀ Abia pẹ̀lụ́ iṣẹ́ àgbẹ̀, nípàtàkì iṣu, àgbàdo, taro, epo pupa, àti pákí. Ilé-iṣẹ́ kékeré kan ń ṣàgbéjáde, pàápàá jùlọ ní agbègbè Aba.[6] Tí ó sì ń gbèrú kíákíá ní iye àti ní Ilé-iṣẹ́, Abia ní ìsopọ̀-ẹlẹ́ẹ̀kẹ́jọ atọ́ka ìdàgbàsókè ènìyàn tó ga jùlọ lórílẹ̀ èdè.[7]

Remove ads

Àwọn Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀

Àwọn Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ (17):

Awon eeyan pàtàkì

Itokasi

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads