Akátá

From Wikipedia, the free encyclopedia

Akátá
Remove ads

Akátá (Acinonyx jubatus; /ˈtə/) jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹbí ológbò tó tóbi jùlọ tí wọ́n sì pọ̀ lórílẹ̀ alààyè. ológbò Ẹ̀yà ẹranko yí wópọ̀ jùlọ ní agbègbè Sàhárà Àríwá ilẹ̀ Adúláwọ̀,Southern, East Africa, àti àwọn díẹ̀ lára ìletò ní orílẹ̀ -èdè Iran. Ẹranko yí fẹ́ràn láti máa gbé ní àwọn orílẹ̀ gbígba, níbí tí koríko pẹ́ṣẹ́pẹ́ṣẹ́ wà. [1]

Quick facts Ipò ìdasí, Ìṣètò onísáyẹ́nsì ...
Akátá
Remove ads

Ìrísí rẹ̀

Akátá jẹ́ ẹranko tí ó ní àwọ̀ àmúlù-málà oríṣiríṣi bí awọ̀ Yẹ́lò, funfun, tí awọọ̀ dúdú ara rẹ̀ sì tó ẹgbẹ́ẹ̀rún méjì níye. Ẹranko yí kìí fi bẹ̀ẹ́ sanra, orí rẹ̀ kò tàbí ó sì rí roboto. Awọ̀ irun dúdú ni ó pààlà tí ó sì yí ojú rẹ̀ po. Àyà ẹranko yí fẹ̀ ó sì jìn sínú díẹ̀ ní ìwọ̀n 70–90 cm (28–35 in) . Ó ga nílẹ̀, ẹsẹ̀ rẹ̀ sì tíínrín, Bákan náà ni ó ní ìrù aláwọ̀ kànákìní tí ó gùn níwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà. Èyí tí ó bá tàbí jùlọ lò ma ń gbésìọ̀n tó 21–72 kg (46–159 lb)[2]

Remove ads

Bí wọ́n ṣe ń ṣọdẹ

Gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ wípé ẹranko yí ni ó yára , tí ó mọ eré sá ju ohunkóhun lọ ní orí ilẹ̀. Ó lè sá iye kìlómítà Mẹ́rìnlélọ́gọ́ta láàrín wákàtí kan, àyà fún ìdinwọ̀n ọ̀nà jíjìn 64 km/h (40 mph) lásìkò tí ó bá fẹ́ pẹran jẹ,ó sì lè sa ìwọ̀n 112 km/h (70 mph) fún ọ̀nà tí kò jìn 100 m (330 ft). Látàrí ìjáfáfá rẹ̀ yí ni kò fi sí ẹranko tó ṣòro fun láti kọlù láì pa.[3]

Àwọn Ìtọ́kasí

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads