Barack Obama

Olóṣèlú From Wikipedia, the free encyclopedia

Barack Obama
Remove ads

Barack Hussein Obama Jr. (ojó-ìbí rẹ̀ ni ọjọ́ kẹrin oṣù kẹjọ ọdún 1961) jẹ́ olóṣèlú àti Ààrẹ Orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Amerika tele.[1] Ó jẹ́ òloṣèlú orílẹ̀ èdè Améríkà, ọmọ ilé ìgbìmó aṣòfin láti ìpínlè Illinois, ọmọ ẹgbé òṣèlú Democrat. Barack Obama jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn òṣèlú méjì tí wón figagbága láti jẹ Ààrẹ ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Ẹni èkejì ni John Mccain. Ni ọjọ́ kẹrin oṣù kọkànlá ọdún 2008 Obama wọlé ìbò fún ipò Ààrẹ ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Obama gorí oyè ní ogún jó osù kinni odún 2009. Barack Obama jé aláwọ̀ dúdú àkọ́kọ́ tí òkan nínú àwọn egbé òṣèlú nlá ti ilè Amẹ́ríkà fún ní ànfàní láti kópa nínú eré ìje àti di Ààrẹ ilè Amerika láti ẹgbẹ́ òṣèlú Democrat.

Quick facts 44th President of the United States, Vice President ...
Remove ads

Ìgbésí ayé

Thumb
Barack àti ìyàwọ́ rẹ̀ Michelle Obama

Wón bí Barack Obama ní ìlú Honolulu, ìpínlè Hawaii ní ọdun 1961. Àwòn òbí ré rí ara won ní ìgbà tí wón nka ìwé ní ilé èkó Unifásítì Hawaii ní ìlu Manoa. Bàba rè wá láti orílè èdè Kenya.[2][3] Barack Hussein Obama- àgbà, lọ ka ìwé nípa òrò ajé ní ilè Amerika. Ìya rè, ènìyàn funfun, ọmọ ilè Améríkà, Stanley Ann Dunham, jé ọmọ ilé èkó Unifásítì láti ìlu Wichitta, ìpínlè Kansas. Àwọn òbí ìya rè lòdì sí àjọṣe àwọn méjèjì, ṣùgbón wón fé ara wọn ní odún 1960.[4] Ọdún méjì léhìn tí wón bí Obama, bàbá rè lọ si Howard fún ìtèsíwájú èkọ rè, ṣùgbón kò mú ẹbí rè lọ nítorí àìsí owó. Ní àìpé ọjó wón yapa. Ní ìgbà èkó rè ní Howard, Obama- àgbà fé Ruth Nidesand, ẹni tí ó bá padà sí orílè èdè Kenya léhìn ìparí èkò rè. Ruth Nidesand jé ìyàwó rè ẹ̀kẹ́ta, wón sì ní ọmọ méjì. Ní orílè èdè Kenya, Obama- àgbà bèrè iṣé ní ilé iṣé tí ó nwa epo ròbì, léhìn èyí, ó ṣiṣé fún ìjọba, gégébí olóòtú ètò ọrò ajé. Ó fi ojú kan ọmọ rè, Obama, ní ìgbàkan péré- ní ìgbà tí oní tòhún pé ọmọ ọdún méwàá. Obama- àgbà fi arapa nínú àgbákò ọkò nípa èyí tí ó sọ ẹsè méjèjì nù. Ní ìgbà tí ó pé ọmọ ọdún mérin-dí-láàdóta, ní ọdún 1982, ó sọ èmí rè nù nínú àgbákò ọkò.

Léhìn ìyapa pèlu bàba Obama, ìya rè fé Lolo Soetoro, ọmọ ilé èkó gíga unifasiti láti orílè èdè Indonesia. Ní ọdún 1967 ó sì bá Lolo Soetoro lọ sí Indonesia. Barack Obama ní ọbàkàn, obìnrin, ọmọ Lolo àti Stanley Ann. Stanley Ann Dunham pèhìndà ní ọdún 1995.

Remove ads

Ìwé tó kọ

  • Obama, Barack. Dreams from My Father: A Story of Race and Inheritance, Times Books, 1995. Reprint edition, 2004; ISBN 1-4000-8277-3
  • Obama, Barack. The Audacity of Hope: Thoughts on Reclaiming the American Dream, Crown, 2006. ISBN 0-307-23769-9.

Àwọn ibùdó lori Interneti

Àwọn ìtọ́kasí

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads