Bethlehem

From Wikipedia, the free encyclopedia

Bethlehemmap
Remove ads

Bethlehem ( /ˈbɛθlɪhɛm/; Lárúbáwá: بيت لحم Hébérù: בֵּית לֶחֶם [[Modern Hebrew phonology|Àdàkọ:Transliteration]]) jẹ́ ìlú ńlá kan tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Palestine ní apá ìwọ̀ Oòrùn Ìpínlẹ̀ tí ó tó kìlómítà mẹ́wá convert|10|km|mi|abbr=in}} sí ìlànà Oòrùn Jerusalem. Iye àwọn olùgbé ibẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́kanlélẹ́gbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn (25,000),[3][4] orílẹ̀-èdè náà. Ibẹ́ ni wọ́n fẹnu kò sí wípé wọ́n ti bí Jésù ní inú abúlé kan tí ó wà níbẹ̀ tí wọ́n ń pe ní Nazareth . Ohun tí jẹ́ nkan àmúṣọrọ̀ àwọn ènìyàn Bethlehem ni ìrìn-àjò ìgbafẹ́ pàá pàá jùlọ lásìkò ọdú Kérésìmesì tí àwọn ẹlẹ́sì ìgbàgbọ́ ma ń ṣe abẹ̀wò sí ibẹ̀ pàá pàá jùlọ Church of the Nativity.[5][6] Ibi tí ó tún ṣe pàtàkì ní ìlú yí ni [Ibojì [Rachel]], èyí tí ó wà ní ẹnu abáwọlé gúsù ìlú Bethlehem, bí óbtilẹ̀ jẹ́ wípé àwọn ọmọ ìlú kìí fi bẹ́ẹ̀ láànfàní sí ibẹ̀ látàrí bí àwọn èniyàn Islreali ṣe gbégi dínà ibẹ̀. Ìgbà akọ́kọ́ tí wọ́n dárúkọ ìlú Bethleme ni ní ọdún 1350-1330 BCE tí wọ́n fi lẹ́tà kan ránṣẹ́ nígbà tí àwọn ọmọ Kánáánì ṣì ń gbé ibẹ̀. Nínú Bíbélì Hebrew, ni won ti ṣàlàyé bí wọ́n ṣe kọ́ Bethlehem gẹ́gẹ́ kí ó lè jẹ́ ààbò fún ìlú Rehoboam,[7] ìlú Rehoboam yí ni wọ́n fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé wọn ti da òróró lé Dafídì lórí gẹ́gẹ́ bí Ọbailẹ̀ Isírẹ́lì. Ìyìnrere Mathew àti Lúùkù ni ó sọ wípeé inú ìlú Bethlehem ni wọ́n ti bí Jésù. Ọba Hadrian ba ìlú Bethlehem jẹ́ lásìkò ọ̀rùndú kejì nínú ogun Bar Kokhba revolt; àmọ́ tí Ọbabìnrin Helena, tí ó jẹ́ Ìyá fún Constantine the Great, ni ó ṣe ìfilóọ́lẹ̀ kanọ́ ilé ìjọsì agbàyanu Church of the Nativity ní ọdún 327 CE.

Quick Facts Arabic transcription(s), • Arabic ...
Thumb
Bethlehem and surroundings from the air in 1931

Àwọn Samaritan tún ba ilé ìjọsìn náà bàjẹ́ gidigidi lásìkò ogun 529, àmọ́ Ọba Justinian I ṣe àtúnkọ́ rẹ̀ lẹ́yìn ọ̀rùndún kan tí Ogun náà wáyé.

Ìlú Bethlehem di ìkan lára ìlú amọ́nà àwọn Mùsùlùmí lábẹ́ àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí Jund Filastin lẹ́yìn tí wọ́n gba ilẹ̀ náà ní ọdún 639. Wọ́n sì ṣàkóso Ìlú náà títí di ọdún 1099 tí àwọn ọmọ ogun onígbàgbọ́ Crusader tí wọ́n yí ìlànà ìjọsìn ìlú náà padà sí ti Latin láti ede èdè Látìnì.

Láàrín ọ̀rùndún kẹtàlá, àwọn ọmọ ogun Mamluks wó odi ìlú náà, àmọ́ wọ́n tún odi ìlú yí kọ́ padà lábẹ́ ìjọba Ottomans níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rùndún kẹrìndínlógún.[8] Ìṣàkóso ìlú Bethlehem kúrò láti ọwọ́ ọba Ottomans bọ́ sí ọwọ́ àwọn Bríténì níparí ogun agbáyé ẹlẹ́keji. Wọ́n da ìlú Bethlehem mọ́ ìjọba Jọ́dání lásìkò ogun tí ó wáyé láàrín àwọn Lárúbáwá àti Isreal ní ọdún 1948, àmọ́ tí àwọn Isreal mókè nínú ogun náà ní ọdún 1967 tííṣe ogun ọjọ́-mẹ́fà. Láti ọdún 1995 ni ìjọba Palestine ti ń ṣe akóso lórí ìlú Bethlehem. [8] Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ìlú Bethlehem jẹ́ ìlú tí àwọn Mùsùlùmí pọ̀ sí jùlọ, síbẹ̀ àwọn ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ náà kò gbẹ́yìn. [9][10] Àwọn olùgbé ati ọmọ orílẹ̀-èdè Isreal ti ta àtaré sí inú ilẹ̀ Bethlehem tí wọ́n sì lé àwọn Mùsùlùmí ati onígbagbọ́ tí wọ́n gbé níbiẹ̀ ní ìrẹ̀pọ̀, wọ́n sì tún ń di ìjẹ inú wọn lọ́wọ́ pẹ̀lú.[11]

Remove ads

Ìpìlẹ̀ orúkọ ìlú yí

Bethlehem (Hébérù: בֵּית לֶחֶם), jẹ́ ìlú ńlá kan tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Palestine ní apá ìwọ̀ Oòrùn orílẹ̀-èdè náà. Ibẹ́ ni wọ́n fẹnu kò sí wípé wọ́n ti bí Jésù ní inú abúlé kan tí ó wà níbẹ̀ tí wọ́n ń pe ní Nazareth . Bethlehem tí ìtumọ̀ rẹ̀ ń jẹ́ Ilé búrẹ́dì tàbí ilé oúnjẹ.[12] Wọ́n ń pe ìlú ní èdè Èdè Grííkì Ayéijọ́un: Βηθλεέμ Àdàkọ:IPA-grc, ati ní èdèLátìnì: Bethleem.[13] Ibi akọ́kọ́ tí wọ́n ti kọ́kọ́ dárúkọ Bethlehem gẹ́gẹ́ àyè kan ni nínú atẹ̀jíṣẹ́ Amarna correspondence (c.1400 BCE), ní èyí tí ó tọ́ka sí ibẹ́ gẹ́gẹ́ bí Bit-Laḫmi,[14] orúkọ tó jẹ́ wípé wọ́n fàá yọ láti ibi tí a kò lẹ̀ tọ́ka sí. Amọ́, àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé orúkọ náà ni wọ́n yọ láti Mesopotamian tàbí Canaanite tí wọ́n ń pè ní Laḫmu tí ń ṣe ọláọ́run afúnilóyún.[15][13][16] Onímọ̀ nípa Bíbélì ìyẹn William F. Albright gbàgbọ́ wípé àgbàsílẹ̀ ètò tí ọ̀jọ̀gbọ́n Otto Schroeder, ni ó "ṣe rẹ́gí".[lower-alpha 1] Albright sọ wípé ìṣẹnupè Lahmu ni ó ti wà bẹ́ẹ̀ láti fún ẹgbàajìdínlẹ́ẹ̀dẹ́gbẹ̀ta ọdún àmọ́, wọ́n ń lòó fún oríṣiríṣi ìtumọ̀ bíi "Tẹ́mpílì ọlọ́run Lakmu" ní Kénáánì, 'Ilé Búrẹ́dì' ní èdè Hebrew àti Èdè Árámáìkì, wọ́n tún ń pèé ní 'Ilé ẹran jíjẹ' ní èdè Èdè Lárúbáwá. Nígbà tí àgbékalẹ̀ "[17] Schroeder's kò jẹ́ ìtànẹ́wọ́ gbà, láti lè jẹ́ kí rẹ́sẹ̀ walẹ̀ ìwádí rẹ̀ nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀.[18] Àwọn àríwísí yí ni ó níṣe pẹ̀lú ìpìlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ l-h-m, tí ó túmọ̀ sí "ìjà" àmọ́ èrò yí kò múnádóko.[12][19]


Remove ads

Àwọn ìtọ́ka sí

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads