Caroline Danjuma
Òṣéré orí ìtàgé From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
Caroline Danjuma, tí a mọ̀ tẹ́lẹ̀ bi Caroline Ekanem, jẹ́ òṣèré ọmọ Nàìjíríà kan. Ó ṣe ìṣàfihàn àkọ́kọ́ rẹ̀ lóju amóhù-máwòran ní ọdún 2004, níbi tí ó ti kópa nínu àwọn gbajúmọ̀ fíìmù kan láti ọwọ́ Chico Ejiro. Lẹ́hìn fífi iṣẹ́ fíìmù sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, ó ṣe ìpadàbọ̀ ní ọdún 2016, tí ó sì kópa nínu eré afìfẹ́hàn aṣaragágá kan ta pe àkọ́lé rẹ̀ ní Stalker, èyí tí ó ṣe pé òun náà ló ṣe àgb́ejáde rẹ̀.
Remove ads
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
Caroline ni a bí sí ọwọ́ bàbá tí n ṣe ọmọ orílẹ̀-èdè Skọ́tílàndì àti ìyá rẹ̀ tí n ṣe ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1][2] Òun ni àkọ́kọ́ àwọn ọmọ mẹ́ta ti òbí rẹ̀.[3] Ó kẹ́ẹ̀kọ́ ìṣàkóso ààbò àyíká, ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ayé àti ṣ́iṣètò agbègbè ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti Calabar.[4] Ó tún gba ìwé-ẹ̀rí àṣeyọrí nínu ìmọ̀ ìhùwàsí ààjọ láti Edinburgh Business School ní ọdún 2016.[5][6]
Iṣẹ́ òṣèré rẹ̀
Nípasẹ̀ Rita Dominic, Chico Ejiro ṣe àfihaǹ Danjuma níbi fíìmù 2004 kan Deadly Care. Lẹ́hìn náà ló kópa nínu àwọn fíìmù aláṣeyọrí míràn tó fi mọ́ Deadly Kiss (2004), Missing Angel (2004), The Captor (2006), Foreign Affairs, Real Love, The Twist, A Second Time àti The Beast and the Angel. Fíìmù titun rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde ni Stalker, tó n sàfihàn Jim Iyke àti Nse Ikpe Etim.Ní Oṣù Kẹẹ̀jọ Ọdún 2017, ààjọ Pan-African kan dá Danjuma lọ́lá fún àwọn ètò àgbàwí rẹ̀ tí ó dá lóri mímú ìlọsíwájú bá àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà.[7]
Remove ads
Ìgbé ayé rẹ̀
Danjuma di ẹni tí kìí kópa mọ́ lóòrèkóòrè nínu eré Nollywood lẹ́hìn ìgbéyàwó rẹ̀ pẹ̀lu Musa Danjuma, àbúrò Theophilus Danjuma ní ọdún 2007.[8][9] Àwọn tọkọtaya náà ní àwọn ọmọkùnrin méjì àti ọmọbìnrin kan.[10] Wọ́n pínyà ní ọdún 2016.[11]
Àríyànjiyàn lóri ọjọ́ orí rẹ̀
Bótilẹ̀jẹ́pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àtẹ̀jáde n tọ́ka sí ọdún bíbí rẹ̀ láti jẹ́ ọ̀kan láàrin 1980 tàbí 1981,[12] Danjuma ti sọ láìmọye ìgbà pé 26 Oṣù Kẹẹ̀fà, Ọdún 1987 ni ọjọ́ ìbí òun.[13][14][15]
Àwọn ìtọ́kasí
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads