Chike Obi
Akéwì ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
Chike Obi /θj/ (April 17, 1921 – March 13, 2008) jẹ́ Olóṣèlú, Onímọ̀ Mátì àti ọ̀jọ̀gbọ́n ọmọ orílẹ̀ ède Nàìjíríà nígbà ayé rẹ̀.[1] Chike Obi ni ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àkọ́kọ́ láti gba àmì ẹ̀yẹ Dókítà nínú ìmọ̀ mátì.[2] Obi ti kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé àti journals nípa Mátì àti ìṣèlú ní Nàìjíríà.[3]
Remove ads
Ìpìlẹ̀ àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
Obi lọ ìwé ní oríṣi àgbègbè ní Nàìjíríà kí ó tó kàwé nípa ìmọ̀ Mátì ní Yunifásítì London.[4] Ní kété tí ó gba àmì ẹyẹ degree àkọ́kọ́, a fun ní ànfàní ọ̀fẹ́ láti ṣe ìwádìí ní Pembroke College, Cambridge, lẹ́yìn náà, tí ó kàwé gboyè Dókítà ní Massachusetts Institute of Technology[5] ti Cambridge, Massachusetts, Orílẹ̀ èdè America, èyí tí ó sọ ọ́ di ọmọ Nàìjíríà àkọ́kọ́ láti gba àmì ẹyẹ Dókítà nínú ìmọ̀ Mátì.[6]
Remove ads
Lẹ́yìn ikú rẹ̀
Obi fi ayé sílẹ̀ ní ọdún 2008, ìyàwó rẹ̀, Belinda, ẹni tí ó jẹ́ Nursì náà fi ayé sílẹ̀ ní ọdún 2010, àwọn méjèèjì fi ọmọ mẹ́rin sáyé.
Àwọn Ìtọ́kasí
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads