D'banj

From Wikipedia, the free encyclopedia

D'banj
Remove ads

Dapo Daniel Oyebanjo tí a bí ni ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù kẹfà, ọdún 1980 ní Zaria, Ipinle Kaduna, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó gbajúmọ̀ gẹ́gẹ́ bíi D'banj jẹ́ akọrin àti oníṣòwò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni oludásílẹ̀ Mo' Hits Records, tí Don Jazzy jẹ́ aṣàgbéjáde orin ní ilé-iṣẹ́ náà. Ó ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì-ẹ̀yẹ̀, díẹ̀ lára wọn ni; akorin ilè Africa tó dára jù lọ ní MTV Europe Music Awards 2007,[1] akọrin toh dára jù lọ ní ọdún 2009 ní MTV Africa Music Awards 2009,[2] òṣèré tó dára jù lọ ni àgbáyé ní 2011 BET Awards, àti akọrin ilẹ̀ Africa tó nh tà jù ní 2014 World Music Awards.

Quick facts Background information, Orúkọ àbísọ ...

Oyebanjo mú orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ tí ń ṣe D'banj láti ara orúkọ àkọ́kọ́ rẹ̀, Dapo àti orúkọ bàbá rẹ̀, Oyebanjo. Ó di gbajúgbajà látara orin "Oliver Twist" tó kọ ní ọdún 2012.

Remove ads

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀

D'banj, tí àwọn èèyàn mọ̀ sí Kokomaster tàbí Bangalee, ni a bí ni ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù kẹfà, ọdún 1980 ní Zaria, apá Àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Bàbá rẹ̀ jẹ́ ajagun orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbà kan rí, ìyá rẹ̀ sì jẹ́ oníṣòwò láti ìlú Shagamu, ní Ogun. D'banj ní àwọn àbúrò tó jẹ́ ìbeji, Taiwo àti Kehinde Oyebanjo.[3]

Ìbẹ̀rẹ̀ orin kíkọ

Femi Oyebanjo, tí ń ṣe ẹ̀gbọ́n D'banj ló sọ D'banj di ẹni tó nífẹ̀ẹ́ orin kíkọ. Femi kú nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún nínú ọkọ̀ òfurufú kan tó já .[4] Ìfẹ́ tí D'banj ní sí orin kíkọ borí ìtakò tó dojuhkọ láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ̀. Oh tiraka láti gba àṣẹ lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ̀, ìtàn yìí wà nínú orin rẹ̀ kan All Da Way.[5]

Lẹ́yìn ikú ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ó mú dùrù ẹ̀gbọ́n rẹ́, ó sì máa ń lò ó láti fi kọrin ní ilé-ilwé rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ló máa ń wá tẹ́tí si. Ó tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ láti lọ kọ́ mechanical engineering ní Lagos State University, àmọ́ kò parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ nítorí ìdaṣẹ́sílẹ̀ àwọn olùkọ́. Ó lọ sí ìlú London láti lọ parí ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ibẹ̀ ló ti pàdé Don Jazzy, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ aṣógbà ní ilé-iṣẹ́ náà. Don Jazzy ràn án lọ́wọ́ láti gbé orin àkọ́kọ́ rẹ̀ "Tolongo" jáde.[6]

Remove ads

Àwọn ìtọ́kasí

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads