Don Jazzy
From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
Michael Collins Ajereh (tí a bí ní ọjọ́ 26, oṣù kọkànlá, ọdún 1982), tí a mọ̀ mọ́ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i Don Jazzy,jẹ́ aṣàgbéjáde rẹ́kọ́ọ̀dù ní Nàìjíríà , aṣojú fún àwọn ilé-iṣẹ́ , onímọ̀ ẹ̀rọ ohùn , ọ̀gá ilé-iṣẹ́ orin, olórin , olókòwò, olùsọdimímọ̀ àti adẹ́rínpòṣónú. Òun ni olùdásílẹ̀ àti ọ̀gá ilé iṣẹ́ Mavin Records.[1] Don Jazzy jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí wọ́n ni ilé-iṣẹ́ orin tí ó ti kógbá wọlé Mo' Hits Records pẹ̀lú Dbanj. Àbúrò rẹ̀ lọ́kùnrin ni D'Prince.
Remove ads
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀
A bí Don Jazzy gẹ́gẹ́ bí Micheal Collins Ajereh ní Umuahia, Abia State, ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù kọkànlá, ọdún 1982,[2] ọmọ ọkùnrin tí Collins Enebeli Ajereh àti Mrs Ajereh bí . Bàbá rẹ̀ wá láti Isoko ní Delta State. Ìyá rẹ̀ jẹ́ Ọmọọba Igbo láti Ìpínlẹ̀ Abia nígbà tí bàbá rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ará Isoko .[3] D'Prince ni àbílẹ́yìn Don Jazzy lọ́kùnrin. Ìdílé Don Jazzy kó lọ sí Ajegunle, Èkó Ní ibi tí wọ́n ti tọ́ Don Jazzy.[4]
Remove ads
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀ àti ẹ̀kọ́
Ìdílé Ajereh kó lọ sí Ajegunle, Èkó, níbi tí wọ́n ti tọ́ Don Jazzy .[5] Ó kàwé ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga takọtabo, Federal Government College Lagos. Ìfẹ́ tí Don Jazzy ní sí orin bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà kékeré, nígbà tí ó sì pé ọdún méjìlá, ó bẹ̀rẹ̀ sí ni ta gìtá, ó sì ń tẹ dùùrù. Ó tún kọ́ nípa àwọn ohun èlò orin tiwantiwa àti àwọn èyí tí ó ní okùn. Don Jazzy lọ kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìmọ̀ ìmójútó okòwò ní Yunifásítì Ambrose Alli , Ekpoma, Ìpínlẹ̀ Ẹdó.
Ní ọdún 2000, ìbátan Jazzy pè é kí ó wá lu ìlù fún ìjọ agbègbè ní London, èyí sì jẹ́ ìrìn àjò kìíní rẹ̀ lọ sí London.[6] Don Jazzy rí iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí i abániṣọ́lé ní McDonald's. Ó tẹ̀ síwájú nínú ìfẹ́ rẹ̀ sí orin , ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Solek, JJC Skillz, Kas, Jesse Jagz, The 419 Squad ati D'banj.
Remove ads
Ìgbé-ayé lọ́kọláya
Don Jazzy fẹ́ Michelle Jackson ní ọdún 2003. Ó jẹ́ kí ó di mímọ̀ pé àwọn ní àwọn ìṣòro nípasẹ̀ bí òun ṣe jẹ́ alákínkanjú ènìyàn tí ó ń lé iṣẹ́, wọ́n sì pínyà lẹ́yìn ọdún méjì tí wọ́n ṣe ìgbéyàwó. Ṣùgbọ́n ṣá, kò sí nínú ètò rẹ̀ láti fẹ́ ìyàwó mìíràn ní kíákíá nítorí ìbẹ̀rù rẹ̀ pé ìfẹ́ àti ìfinjì rẹ̀ fún orin lè tún dá ègbodò fún ìfẹ́ ẹlòmíràn sí í. [7][8]
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads