Dorra Zarrouk
From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
Dorra Ibrahim Zarrouk (Lárúbáwá: درة إبراهيم زروق, bíi ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kìíní ọdún 1980)[1] jẹ́ òṣèré lórílẹ̀-èdè Tunisia.[2][3][4][5]
Remove ads
Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀
Wọ́n bí Dorra sí ìlú Tunis. Bàbá rẹ̀ ni Ibrahim Zarrouk, bàbà ìyá rẹ̀ sì ni Ali Zouaoui tí ó jẹ́ òṣèlú.[6][7] Dorra gboyè nínú ìmò òfin àti òṣèlú láti ilé ẹ̀kọ́ gíga tí Saint Joseph University ní Lebanon ní ọdún 2003.[8][9][10]
Iṣẹ́
Dorra bẹ̀rẹ̀ eré ṣíṣe ní ọdún 1997.[11] Ní ọdún 2020, ó kópa nínú eré Khorma.[12] Ní ọdún 2003, ó farahàn nínú eré Colosseum: Rome's Arena of Death[13]. Eré orí tẹlẹfíṣọ̀nù tí ó má kọ́kọ́ ṣé ni orílẹ̀ èdè mìíràn yàtọ̀ sí Tunisia ni Fares Bani Marwan ní orílẹ̀ èdè Syria ní ọdún 2004. Lára àwọn eré tí ó tí ṣe ni Al Mosafer, Tisbah Ala Khair àti Sheikh Jackson.[14][15]
Ìgbésí ayé rẹ̀
Dorra fẹ́ Qays Muktar ní ọdún 2012.[16] Ní ọdún 2020, ó ṣe ìgbéyàwó pelu Hany Saad.[17][18]
Àwọn Ìtọ́kàsi
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads