Funke Akindele

Òṣéré orí ìtàgé From Wikipedia, the free encyclopedia

Funke Akindele
Remove ads

Funke Akindele tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹjọ ọdún 1977 [1]tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ń Jennifer jẹ́ òṣèrébìnrin àti olóòtú sinimá [2]àgbéléwò ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Wọ́n bí Fúnkẹ́ sí ìlú Ìkòròdú, ní ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà . Eré orí tẹlifíṣọ̀n kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "I need to know" ló mú un di gbajúmọ̀ ìlúmọ̀ọ́kà òṣèrébìnrin lọ́dún 1998 sí ọdún 2002. Lọ́dún 2009, ó gba àmìn ẹ̀yẹ tí "Africa Movie Academy Award" gẹ́gẹ́ bí òṣèré tó dára jùlọ. Sinimá àgbéléwò kan tí òun fúnra rẹ̀ kọ, tí ó sìn ṣe agbátẹrù rẹ̀, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Jennifer" mú un gbajúmọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí àwọn ènìyàn fi fún ní orúkọ ìnagijẹ, "Jennifer" tí gbogbo ènìyàn ń pè é. Lẹ́yìn èyí, ó tún ń ṣe sinimá aláwàdà tí ó pè ní "Jennifer Diary", sinimá yìí mú un gba àmìn ẹ̀yẹ òṣèrébìnrin aláwàdà tó dáńgájíá jùlọ lọ́dún 2016.[3] Fúnkẹ́ Akíndélé tí kópa nínú sinimá àgbéléwò to tì ju ọgọ́rùn-ún lọ. [4] [5] [6] [7]

Quick Facts Ọjọ́ìbí, Iléẹ̀kọ́ gíga ...
Remove ads

Ààtò àwọn àmìn ẹ̀yẹ tí ó ti gbà

More information Ọdún, Ètò ...
Remove ads

Àwọn Ìtọ́kasí

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads