Ilú-ọba Ọ̀yọ́
From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
{Ìkọ kedere''''Ìkọ kedere'{Short description|Former empire in present-day Benin and Nigeria}}


Àdàkọ:Ilé Odùduwà Ilẹ̀ Ọba Ọ̀yọ́ jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ilẹ̀ Yorùbá ni apá iwọ̀ Oorùn ilẹ̀ Adúláwọ̀. Ìdàgbàsókè Ilẹ̀ Ọba Ọ̀yọ́ kó sé lẹ́yìn bí wọn ṣe ní àgbékalè oun ìtọ̀sẹ̀ ìṣèjọba tó lọọrin ti wọn fi ń tòlú àti àwọn ìlú amọ̀nà tí wọn wà lábé ìṣàkóso wọn láyé àtijọ́ . Bákan náà ni wọn ṣe àmúlò àwọn ìfẹsẹ̀múlẹ̀ okòwò tó múlẹ̀ ṣinṣin àti bí wọn ṣe ní àwọn ọmọ ogun tí wón lè lẹ́gbẹ̀rún légbẹ̀rún
Láàriǹ ọ̀rúndún ẹtàdínlógun si ọ̀rúndún kejìdínlógún sẹ́yìn , Ilé ọba Ọ̀yọ́ ni ó ni ètò ààbò tó múná dúró ṣinṣin . Gbogbo àwọn ìlú tí ó sì ku tí jẹ́ ọba ní wón sí wa láti wá darapọ̀ mọ́ àwọn ilẹ̀ ọba Ọ̀yọ́ .
Lára àwọiléié ọba wòọyí nii Fon, ilẹ ọba Kingdom of Dahomey ti o ti di orílẹ̀-èdè Benin loni.
Remove ads
Ìtàn ilè Ọba Ọ̀yọ́
Àwọn akọni ìwáṣẹ̀
Àdàkọ:Yoruba people Itan ilẹ Ọba Ọyọ bẹrẹ lati ori olupilẹṣẹ rẹ ti gbogbo ènìyàn mọ si Ọ̀rányàn tabi Ọ̀rànmíyàn ti o jẹ abikẹyin Oduduwa ni (Ilé-Ifẹ̀). Gẹgẹ bi itan ti ṣe sọ, Ọranmiyan ṣe ipinu pẹlu awọn ẹgbọn rẹ lati kọ ẹgbin ti o ta le baba re ti n ṣe Oduduwa lati ọdọ awọn alamulegbe wọn nipa kikogun ja wọn. Nigba ti wọn n lọ soju ogun naa, awọn t'ẹgbọn t'aburo ba ni ede aiye-ede laarin ara wọn ni gbogbo wọn ba fi pínyà ti wọn si lọ lọtọọtọ pẹlu awọn ọmọ ogun ikọọkan wọn.[2] Latari eyi, awọn ọmọ ogun ti Ọranmiyan kere jọjọ lati tẹ siwaju lori ipinu ọkan re nipa ogun naa mọ, fun idi eyi ni oun ati awọn ọmọ ogun rẹ ba fi rin titi won fi de bebe odò Niger River ti wọn si fi de ilu Ibusà (Bussa). Ilu yi ni awọn alaṣẹ ibẹ ti gbaa ni alejo ti wọn si ro lagbara pẹlu bi wọn ṣe so ejò kan ti wọn fi oogun pese rẹ mọọ lọrun.
Awọn alaṣẹ ti wọn gba Ọranmiyan lalejo si sọ fun wipe ki o tẹle ejo naa titi de ibi ti ejo naa yoo duro lo ojọ meje ti yoo si wọnu ilẹ lọ. Ọranmiyan tẹle amọran wọn, ibi ti ejo naa wọlẹ si, ibẹ naa si ni wọn tẹ ibi ti o di ilu Ọ̀yọ́ loni. Ọgangan ibi ti ejo yi wolẹ si ni wọn n pe ni Àjàká loni. Ọ̀ranmiyan tẹ ilu Ọyọ, oun naa si ni o kọkọ jẹ Ọba ti wọn si n pee ni "Alàafin Ọ̀yọ́" .[3]
Nigba ti wọn n kọ Ọyọ lọwọ, awọn ọmọ ogun Bariba gbogun lati gba ilu tuntun naa, amọ Ọrangun Ajagunla lati ile-Ila ti o jẹ ẹgbọn fun Ọranmiyan ni o ko awọn ọmọ ogun wa lati gbeja aburo rẹ ti o si gba ilu Ọyọ lọwọ awọn ọmọ ogun Bọ̀gú. Ko pẹ ti Ọranyan jagun ajaṣẹ ni iyawo re Torosi ti o jẹ ọmọ oba Nupe bi ọmọ ọkunrin kan fun, ti o si sọ orukọ rẹ ni Ajuwọn Ajaka. Lẹyin igba diẹ, ni Torosi tun bi ọmọ ọkunrin miran ti wọn pe ni Arabambi ti wọn n pe ni Ṣàngó. Gẹgẹ bi itan ṣe sọ, Ṣango jẹ oruko ti Arabambi gba lati ọdọ baba iya rẹ ti o tumọ si ọlọrun Àrá.
Ibẹrẹ ọdun (13th century sí 1535)
Ibẹrẹ ọdun 1300 CE (common era), ni awọn onimọ sọ wipe wọn da ilu Ọyọ silẹ.[4] Alaafin Ajuwọn Ajaka ni o gba ipo Ọba lẹyin Ọranmiyan, amọ wọn yọọ nipo nitori wipe Ajuwọn Ajaka o fẹran alaafia ti ko si nigbagbọ wipe ogun ni o le yanju aawọ ti o ba ṣẹlẹ, ati wipe o faye gba gbogbo awọn oloye re lati ṣe ohun ti o ba wu wọn ninu ilu. [5] Ẹni ti wọn fi jọba lẹyin rẹ ni Àjàká ti a mọ si Ṣàngó, ti awọn eniyan pada sọ di òrìṣà mọ̀nà-mọ́ná leyin ikú rẹ. Lẹyin eyi ni Ajaka pada sori apeere ọba ti oun naa si di arogunmasa, arogun malelo ati arogunyọ. Lẹyin Ajaka ni Alaafin Kori gorin itẹ ti o si jagun gba ilu ọpọ ilu ti àwọn ilu ti o di igboro Ọyọ lonii. [3]
Ọ̀yọ́ Ilé
Ọ̀yọ́ Ilé ni aarin gbungbun ilu Ọyọ, ibẹ naa si ni wọn tun n pe ni Ọyọ Katunga, Ọyọ Atijọ' tabi Ọyọ-Oro [6] Ile tabi aye ti o ṣe pataki julọ ni Ọyọ ni Ààfin ati ọjà-Ọba. Wọn mọ odi yika gbogbo enu iloro ati aala igboro Ọyọ ti ẹnu abawọle rẹ si jẹ mẹtadinlogun. Aafin ati Ọja-Ọba yi ni wọn n fi pataki Ọba Ọyọ han, yala fun eni ti o je ọmọ ilu tabi alejo. Lẹ́yìn ìgbà tí ìjọba Fulani gba ìjọba lọ́wọ ilẹ̀ ọba Ọ̀yọ́ , ni a dá Ọ̀yọ́ sílẹ̀ láti dúró gẹ́gẹ́ bí ìtàn fún gbogbo ọmọ adúláwò .
Ija akoso llu Ọyọ gba
Ni nkan bi ọdun 1535, awọn alagbara ile Nupe ja iṣakoso ilu Ọyọ gba nigba ti Tsoede ti o jẹ adari ọmọ ogun Nupe le Alaafin Onigbogi ati awọn ìjòyè rẹ kuro ti wọn sì sa lọ si ile Ọba Bogu tabi Ibariba. [7][8] Tsoede ati awọn ọmọ ogun re lọ ilu Ọyọ titi di ibẹrẹ ọrundun metadilogun.[9]
Remove ads
Àwọn ìtọ́kasí
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads

