Isaiah Washington
From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
Isaiah Washington IV jẹ́ òṣèrékùnrin ti ilẹ̀ American, àti aṣagbátẹrù fíìmù. Lẹ́yìn ìfarahàn rẹ̀ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ fíìmù, bíi ṣíṣe ẹ̀dá ìtàn Dr. Preston Burke nínú apá kìíní ti fíìmù Grey's Anatomy láti ọdún 2005 wọ ọdún 2007, ó di gbajúmọ̀ òṣèré.
Washington bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ nípa àjọṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn olùdarí fíìmù bíi Spike Lee nínú fíìmù Crooklyn (1994), Clockers (1995), Girl 6 (1996), àti Get on the Bus (1996). Ó tún farahàn nínú Love Jones (1997), Bulworth (1998), Out of Sight (1998), True Crime (1999), Romeo Must Die (2000), Exit Wounds (2001), Ghost Ship (2002), àti Hollywood Homicide (2003).
Ní ọdún 2020, Washington di olóòtú ètò kan lórí Fox Nation.[2] Ní ọdún 2022, ó kópa nínú fíìmù Corsicana (2022).
Remove ads
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀
Wọ́n bí Washington sí ìlú Houston, ní Texas, níbi tí àwọn òbí rẹ̀ ń gbé ní agbègbè Houston Heights. Àwọn òbí rẹ̀ kó lọ sí Missouri City, ní Texas ní ọdún 1980, níbi tí ó ti jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ gboyè àkọ́kọ́ láti Willowridge High School, ní Houston, ní ọdún 1981. Washington sọ ọ́ di mímọ̀ nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò rẹ̀ pẹ̀lú Star Jones pé ọmọdún mẹ́tàlá ni òun wà, nígbà tí wọ́n pa bàbá òun. Ó darapọ̀ mọ́ He United States Air Force nígbà tí ó wà ní ọmọdún mọ́kàndínlógún, níbi tí ó sì ti ṣiṣẹ́ lórí Northrop T-38 Talon.[3][1]
Remove ads
Àtòjọ àwọn fíìmù rẹ̀
Fíìmù àgbéléwò
Fíìmù orí ẹ̀rọ ayélujára
Remove ads
Àtòjọ àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀
Àwọn ìtọ́kasí
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads