Kayode Adams

From Wikipedia, the free encyclopedia

Remove ads

Kayode Ted Adams (o ku ni Oṣu Kẹwa ọdún 1969) jẹ ajafitafita ọmọ ile-iwe ni Yunifasiti ti Eko (UNILAG) ti o di ẹni àríyànjiyàn ni ọdún 1965 lẹhin ti o gun igbákejì alákóso (VC) ti Fasiti ti Eko, Saburi Biobaku . [1] [2] [3]

Ikọlù sí Saburi Biobaku

Lẹyìn ti aisi isọdọtun ti Ọjọgbọn Eni Njoku gẹgẹ bi Igbákejì Alákóso UNILAG, Ọjọgbọn Saburi Biobaku ni wọn yán gẹ́gẹ́bí VC nipasẹ ijọba Sir Abubakar Tafawa Balewa, Prime Minister ti Naijiria nígbà náà. Ipinnu naa ko jẹ ìtéwógbà láàrin àwọn ọmọ ilé-ìwé UNILAG, ti wọn kẹ́fin ojúsàájú ẹda níbi yíyan Biobaku. [1]

Lásìkò ti Biobaku n gba awujo UNILAG ni iyànjú ni oṣù kẹfà ọdún 1965, Kayode Adams si sunmọ ibi ìpàdé náà ti o si gun Biobaku lẹyìn. [1] Iṣẹlẹ naa yori si aifọkanbalẹ, ti o sí padà yọrisi titipa UNILAG fun ọpọlọpọ àwọn oṣu.

Remove ads

Idanwo

Wọ́n gbé Adams lọ sí ilé ẹjọ́ pé ó gún Biobaku ní ọbẹ, ó gbé ẹ̀sùn aṣiwèrè dìde, ó sì sọ pé òun kò jẹ̀bi. Laibikita ààbò aṣiwèrè rẹ, Adams jẹbi ẹ̀sùn ipaniyan, wọn sí fisi Ile-iwosan ọpọlọ Yaba, wọnsi le kúrò ni UNILAG. [1]

Iku

Wọn bá Adams ni okú ni Bar Beach, wọn sí pinnu pé o mumi yo ni ni oṣù kẹwa ọdún 1969. [4] [5]

Awọn itọkasi

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads