Mons pubis

From Wikipedia, the free encyclopedia

Mons pubis
Remove ads

Ní ìmọ̀ nípa ẹ̀yà ara ènìyàn, àti ní gbogbo àwọn ẹranko tí ó lè bímọ, mons pubis (tí a tún mọ̀ sí  mons, àti ní pàtó lara àwọn obìrin sí mons Venus tàbí mons veneris),[1][2] jẹ́ ibi róbótó tó lọ́rá lókè pubic symphysis ti àwọn egungun pubic.[1][2][3][4][5][6] Ní ara àwọn obìrin, ó maa ń ṣarajọ sí iwájú vulva. Ó pín sí labia majora ("ètè tó fẹ̀") ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì furrow tí wọ́n mọ̀ sí pudendal cleft tí ó yí labia minora, clitoris, urethra, ojú òbò àtí àwọn ẹ̀yà míràn nínú vulval vestibule.[2][5][6]

Quick facts Details, Precursor ...

Ìtóbisí mons pubis kò rí bákan tí ó sì ní ṣe pẹ̀lú ìwọn kẹ́míkà ìtọ́sọ́nàn ara àti ọ̀rá ara, tí ó sì ṣeé rí dáradára lára àwọn obìrin.[1][3]  Lẹ́yìn tí obìrin ba ti bàlágà, irun máa ń bo ojú ẹ̀ tí ó sì máa ń fẹ̀.[4][6][7][8]  Àwọn ọ̀rá inú mons pubis maa ń gbẹgẹ́ sí estrogen, tí ó sì máa ń fa ìṣarajọ òkìtì tí obirin ba ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà.[8] Èyì má a ń ti iwájú labia majora sí ìta kúrò nínú egungun pubic. bẹ́ gẹ́gẹ́,mons pubis má a ń sábà hàn dáradára tí estrogen ara bá ti ń dínkù tí a máa ń rí ti obìrin bá tí ń súmón ojọ́ orí tí wọn kò lè bímọ mọ́.[9]

Orúkọ mons pubis jẹyọ láti èdè Latin fún "pubic mound", àti mons Venus tàbí mons veneris  jẹyọ láti èdè Latin fún "mound of Venus".[1][2]

Remove ads

Àwọn ìtọ́kasí

Àwọn àjápọ̀ látìta

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads