Moody Awori
From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
Moody Arthur Awori (tí a bí ní oṣù Kejìlá ọdún 1928) tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ gẹ́gẹ́ "Uncle Moody", jẹ́ olóṣèlú ọmọ orílẹ̀ ède Kenya tí ó jẹ́ igbá kejì ààrẹ orílẹ̀ ède Kenya láti ọjọ́ Kàrúndínlógbọ̀n oṣù kẹsàn-án ọdún 2003[1] di ọjọ́ kẹsàn-án oṣù Kínní ọdún 2008.[2] Òun ni ó kọ ìwé Riding on a Tiger,.
Remove ads
Òṣèlú
Ipò ijoba àkọ́kọ́ tí a yan Moody Awori sí ni lati ṣe aṣojú Ọkọ̀ Funyula ní Busia District ní ọdún 1984.[1][3] Lábé ààrẹ Daniel arap Moi, o di ọ̀pọ̀lọpọ̀ ipò mú gẹ́gẹ́ bi ìgbá-kejì mínísítà.[1][3]
Awori fi ẹgbẹ́ òṣèlú Kenya African National Union kalẹ̀ láti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú National Rainbow Coalition ní ọdún 2002, ó sì di ipò alága ọkàn lára àwọn ìgbìmọ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú náà.[1] Nígbà tí Moi rọ́pò Mwai Kibaki, Awori di Mínísítà abẹlé ní oṣù Kínní ọdún 2003[3] kí ó tó di ìgbà kejì ààrẹ ní kẹsàn-án 2003, lẹ́yìn ìgbà tí ìgbà kejì ààrẹ tẹ́lẹ̀, Michael Kijana Wamalwa, fi ayé sílẹ̀ ní London.[1]
Remove ads
Àwọn ìtọ́kasí
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads