Naira Marley
From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
Naira Marley tí orúkọ àbísọ rẹ̀ gangan ń jẹ́ Azeez Fáṣọlá, tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹsàn-án oṣù karùn-ún ọdún 1994 (9th May 1994) jẹ́ gbajúmọ̀ olórin àti oǹpilẹ̀kọ̀wé-orin ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [2]Òun ní Ààrẹ ẹgbẹ́ olólùfẹ́ àgàbàgebè rẹ̀ tí wọ́n ń pè ní "Marlians".[3][4] [5]
Remove ads
Ìgbà èwe àti ìkẹ́kọ̀ọ́ ré
Wọ́n bí Naira Marley ní ìlú Agége ní Ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Nígbà tí ó wà lọ́mọdún mọ́kànlá ní o dèrò ìlú òyìnbó, ní Peckam, lápá gúúsù London, lórílẹ̀-èdè Gẹ̀ẹ́sì.[6] Ó kẹ́kọ̀ọ́ ní Porlock Hall kí ó tó tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Walworth School, níbi tí ó ti gbàwé ẹ̀rí General Certificate of Secondary Education. Naira Marley kàwé gbàwé ẹ̀rí tí ó ga jùlọ nínú ìmọ̀ okoòwò ní ilé-ẹ̀kọ́ Harris Academy ní ìlú Peckam Peckham. Ó tún kàwé gbàwé ẹ̀rí nínú ìmọ̀ òfin okoòwò ní ilé-ẹ̀kọ́ giga Crossways College tí wọ́n ń pè ní Christ the King Sixth Form College .[7]
Remove ads
Àtójọ àwọn orin rẹ̀
Orin alájọkò
- Gotta Dance (2015)
- Lord of Lamba (2019)
Orin aládàákọ
- "Issa Goal" (2017)
- "Japa" (2018)
- "Am I A Yahoo Boy" (2019)
- "Opotoyi (Marlians)" (2019)
- "Soapy" (2019)
- "Puta" (2019)
- "Mafo" (2019)
- "Tesumole" (2019)
- "Tingasa" (2019)
Àtòjọ àwọn àmìn-ẹ̀yẹ tí ó gbà àti àwọn tí wọ́n yàn án fún
Àwọn Ìtọ́kasí
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads