Nipsey Hussle

From Wikipedia, the free encyclopedia

Nipsey Hussle
Remove ads

Ermias Joseph Asghedom (August 15, 1985 – March 31, 2019), tó gbajúmọ̀ pẹ̀lú orúkọ ìtàgẹ́ rẹ̀ bíi Nipsey Hussle (ó sábà kọ ọ́ bíi Nipsey Hu$$le), jẹ́ olórin rap, alákitiyan, àti oníṣòwò ará Amẹ́ríkà.[1] Ó gbajúmọ̀ wá láti Los Angeles ní àrin àwọn ọdún 2000, Hussle dá fúnrara rẹ̀ gbé àwo-orin mixtape àkọ́kọ́ rẹ̀ jáde, Slauson Boy Volume 1,[2] èyí ló fàá tí ó fi tọwọ́bọ̀wé àdéhùn pẹ̀lú Cinematic Music Group àti Epic Records.[3][4][5][6]

Quick facts Ọjọ́ìbí, Aláìsí ...

Hussle gbajúmọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àwo-orin mixtape tó gbé jáde, nínú wọn ni Bullets Ain't Got No Name, The Marathon, The Marathon Continues, àti CrenshawJay-Z ra ogọ́rùún nínú wọn fún $100 fún ẹyọkan.[7] Lẹ́yìn ìfàsẹ́yìn, ó gbé àwo-orin rẹ̀ àkọ́kọ́ jáde tó pè ní Victory Lap ní ọdún 2018,[8][9][10][11] wọ́n sì pè lórúkọ fún Ẹ̀bùn Grammy ọdún 2019. Lẹ́yìn tó di olóògbé, wọ́n fún ní Ẹ̀bùn Grammy méjì fún àwọn orin "Racks in the Middle" àti "Higher" (tó ṣe pẹ̀lú DJ Khalid) ní ibi àjọyọ̀ ẹ̀bùn Grammy ọdún 2020.[12]

Ó tún gbajúmọ̀ fún iṣẹ́ òwò rẹ̀, Hussle dá ilé ìtajà Marathon Clothing sílẹ̀, pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ Carless, olórí ilé-iṣẹ́ náà, Karen Civil àti pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n rẹ̀ Samiel Asghedom ní 2017,.[1][13] Ní ọjọ́ 31 oṣù kẹta ọdún 2019, wọ́n yìnbọn pa Hussle ní iwájú ilé-ìtajà rẹ̀ ní Los Angeles.[14] Eric Holder, ọkùnrin ọmọ-ọdún 29 tí òhun àti Hussle ti ní ìjiyàn ní àárọ̀ ọjọ́ náà, ní wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó yìnbọn pá.[15]


Remove ads

Àwọn Ìtọ́kasí

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads