Oba Otudeko
From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
Oba Otudeko CFR tí wọ́n bí ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kẹjọ ọdún 1943 jẹ́ oníṣòwò ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tó jẹ́ olùdásílẹ̀ àti alága Honeywell Group.[1][2] Ó fìgbà kan jé alága FBN Holdings àti olùdásílẹ̀ Oba Otudeko Foundation.[3][4][5][6]
Remove ads
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀
Ayoola Oba Otudeko jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ibadan, ní ipinle Oyo, ní 18 August 1943 sínú ìdílé ọlọ́lá, èyí sì mu kí ó jẹ́ ọmọọba ní ilẹ̀ Yorùbá.[7] Ìyá rẹ̀ jẹ́ oníṣòwò.[8] Ó kẹ́kọ̀ọ́ ní St. John’s School, ní Oke-Agbo,[9] ní Ijebu-Igbo, ní ipinle Ogun, kí ó ṣẹ̀ tó lọ Olivet Baptist High School, ní Oyo.[8] Lẹ́yìn náà, ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Accountancy ní Leeds College of Commerce Leeds, Yorkshire, United Kingdom (èyí tó ti wá wà lára Leeds Beckett University).[10] Oba Otudeko jẹ́ Chartered Banker, Chartered Accountant àti Chartered Corporate Secretary.[11]
Remove ads
Àwọn ìtọ́kasí
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads
