Pọ́rtúgàl
From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
Pọ́rtúgàl (i /ˈpɔrtʃʉɡəl/ Pọrtugí: Portugal), lonibise bi Orileominira Portugal (Pọrtugí: República Portuguesa[8]), je orile-ede to budo si apaguusuiwoorun Europe lori Penisula Iberia. Portugal ni orile-ede to sunmo apa iwoorun julo ni Europe, be sini o ni bode mo Okun Atlantiki ni iwoorun ati ni guusu, bode mo Spain ni ariwa ati ilaorun. Awon isujo erekusu inu Atlantiki, eyun Azores ati Madeira je ara Portugal. Orile-ede yi gba oruko re lati ibi oruko ilu re totobijulo keji, Porto, ti oruko Latini re je Portus Cale.
Ori ile to wa ninu bode Orileominira Portugal loni ti je titedo leralera lati awon igba iwaju itanakole: latowo awon Gallaeci ati awon Lusitanians, o bo si inu Ileobaluaye Romu be sini awon eniyan elede Jemani bi Suevi ati awon Visigoths na tedo sibe, ni orundun 8k awon Mauri bori ibe. Nigba Reconquista awon Elesin Kristi, Portugal seda ara re bi ileoba alominira, tori ni won se unpe bi orile-ede-ajoba togbojulo ni Europe.[9]
Ni orudnun 15k ati 16k, ntoripe o lewaju Igba Iwari, Portugal di ileobaluaye to nile kakiri Afrika, Asia, Oseania, ati Gusu Amerika, lati di ikan ninu awon alagbara itokowo, oloselu ati ologun lagbaye. Ileobaluaye Portugal ni ileobaluaye akariaye akoko ninu itan,[10] ati eyi to pejulo ninu gbogbo awon obaluaye alamusin Europe. Sibesibe, ipo orile-ede ti je riresile gan titi to fi di orundun 19k, agaga leyin ilominira ile Brasil, to je imusin totobijulo re.
![]() |
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Remove ads
Àwọn ìtokasi
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads