Peter Fatomilola
Akéwì ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
Wọ́n bí Peter Fátómilọ́lá' ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kínní ọdún 1946. Ó jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ̀-èdèNàìjíríà, ó sì jẹ́ òṣèré orí ìtàgé, olùkọ̀tàn, akéwì àti ògúná gbòǹgbò níbi ká kọ eré-oníṣe (playwright.)[1]
Remove ads
Ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀
Wọ́n bí Peter Fátómilọ́lá ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kínní ọdún 1946 sí ìjọba ìbílẹ̀ Ìfisàn Èkìtì. Ó jẹ́ ọmọ Olúwo, ní èyí tí a gbàgbọ́ ẃipé ó ṣe okùnfà àwọn ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí babaláwo nínú ọ̀pọ̀ eré orí-ìtàgé ilẹ̀ Naijiria[2]. Ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèré Olókun ní 1967 lábẹ́ àkóso ọ̀jọ̀gbọ́n olóògbé Ọlá Rótìmí, gbajú gbajà òǹṣèré orí-ìtàgé (dramatist) àti olùkọ̀tàn àdídùn ní ilé-ẹ̀kọ́ àgbà ti Ilé-Ifẹ̀ tí wọ́n sọ di Ọbáfẹ́mi Awólọ́wò University[3] Bákan náà ni Peter tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ àgbà Ilé-Ifẹ̀ ìyẹn Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ University, níbi tí òun pàá pàá ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ìmọ̀ Theatre Art ní 1978.[4] Òun náà tún ni ẹni tí ó kọ́kọ́ kópa gẹ́gẹ́ bíi "Papa Ajasco", nínú sinimá àgbéléwò tí ọ̀gbẹ́ni Wálé Adénúgà.[5] ń gbé jáde. Bákan náà ni ó tún ti kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré orí-ìtàgé ilẹ̀ Nàìjíríà tó lààmì laaka gẹ́gẹ́ bí Ṣàngó, tí ó jẹ́ ìtàn akọni ìgbà ìwáṣẹ̀ tí Ọbáfẹ́mi Lasode gbé jáde tí Waĺé Ogunyemi sì ṣe àpilẹ̀kọ rẹ̀ ní ọdún 1997[6]
Remove ads
Ìkópa rẹ̀
- Sango (Film) (1997)
Àwọn Ìtọ́kasí
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads