Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìdánilóró September 11, 2001

From Wikipedia, the free encyclopedia

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìdánilóró September 11, 2001
Remove ads

Awon isele idaniloro September 11, 2001 tabi 9/11 tabi September 11 je awon isele ifikuparaeni eleto atelerawon latowo al-Qaeda lori orile-ede Amerika ni September 11, 2001. Ni aro ojo na, awon oludaniloro 19 omo egbe al-Qaeda fipagba baalu merin.[1][2] Awon oludaniloro yi moomo fi meji ninu awon baalu yi kolu Twin Towers ti Gbongan Idunadura Agbaye ni ilu New York, eyi fiku pa gbogbo awon eniyan inu awon baalu na ati opo awon osise inu awon ile-ise na. Awon ile-ise mejeji yi wo lule larin wakati meji, won fa ibaje si awon ile to wa nitosi won ati awon miran lookan. Awon oludailoro na tun fi baalu keta kolu Pentagonu ni Arlington, ni Virginia, to ko jinna si Washington, D.C.. Baalu kerin jalule si ori papa kan nitosi Shanksville ni oko Pennsylvania leyin ti awon oluwoko melo kan ati awon osise ifoloke gbiyaju lati gba idari baalu na pada, eyi ti awon oludanilo wonyi ti yoju re pada ko ona Washington, D.C. Ko si eni kankan ti ko ku ninu awon ifoloke yi.

Quick facts September 11 attacks, Location ...

Awon eniyan 2,973 tikomowo tikomose ati awon oludaniloro 19 ni won ku nitori isele yi.[3] Ogunlogo awon to ku nibe je omolu, ninu won ni awon ara orile-ede 70 wa.[4] Lapapo mo awon wonyi, iku enikan latowo arun ige ni awon onimo ilera so pe o je nitori fifarakan eruku lati iwolule Gbongan Idunadura Agbaye.[5]

Ifesi orile-ede Amerika si isele yi ni lati pe Ogun si Isedaniloro. O gbori orile-ede Afghanistan lati le awon Talibani kuro, ti won ti fi aaye gba awon oludaniloro al-Qaeda. The Orile-ede Amerika tun sofin USA PATRIOT Act. Bakanna opolopo awon orile-ede ni won fi agbara kun ofin olodi-isedaniloro won, be sini won tun fe awon agbara igbofinro won. Awon ile pasiparo Amerika melo kan ko sise ni awon ojo to ku ni ose na leyin isele yi, be sini won pofo gidigidi leyin ti won bere ise pada, agaga ti awon ile-ise irinna ofurufu ati adiyelofo. Ibaje ti isele yi fa si awon yara ile-ise ni Lower Manhattan fa ibaje si okowo ni be.

Larin odun kan, atunse ti waye si ibaje ni Pentagonu, won si ko Ogiri Iranti Pentagonu sori ibi isele nibe. Igbese atunko ti bere si Ibi Gbongan Idunadura Agbaye. Ni 2006 yara ibise tuntun je pipari lori ibi Ile 7 Gbongan Idunadura Agbaye. Atunko Ile 1 Gbongan Idunadura Agbaye unlo lowo lori ibi isele na besini pelu 1,776 ft (541 m) nigba to ba pari ni 2013, yio je ikan ninu awon ile togajulo ni Ariwa Amerika. Ireti nibere nipe won yio ko gbongan meta larin 2007 ati 2012 sori ibi isele na. Igbele bere fun Ogiri Iranti Apapo Orile-ede fun Ifoloke 93 ni November 8, 2009, be si ni apa kinni re yio pari nigba ajodun kewa isele yi ni September 11, 2011.[6]

Remove ads

Isele/Ijangbon

Thumb
Map showing the attacks on the World Trade Center.
Thumb
The World Trade Center Towers on fire and the collapse of the South Tower
Thumb
View of the World Trade Center shortly after both towers fell

Kutukutu ni aro ni ojo 11 osu kesan odun 2001, awon afipagboko mokandinlogun gba idari baalu merin ti won n lo si San Francisco ati Los Angeles lati Boston, Newark, ati Washington, D.C. (Papa Oko-ofurufu Kakiriaye Dulles).[1] Ni ago 8:46 a.m., baalu Ifoloke 11 ti American Airlines fikolu Ile Ariwa ti Gbongan Idunadura Agbaye, o je titele pelu Ifoloke 175 ti United Airlines to kolu Ile Guusu ni ago 9:03 a.m.[7][8]

Awon afipagboko keji fi baalu Ifoloke 77 American Airlines kolu Pentagonu ni ago 9:37 a.m.[9] Ifoloko kerin, eyun Ifoloke 93 United Airlines jalulole leba Shanksville, Pennsylvania ni ago 10:03 a.m, leyin ti awon oluwoko ninu baalu yi bere ija pelu awon afipagboko. Won gba pe awon oludaniloro na fe fi lo kolu boya Kapitol (ile to je ti Igbimo Asofin Orile-ede Amerika) tabi White House.[10][11]

Ninu ifoworowanilenuwo ti Yosri Fouda, an oniroyin al Jazeera se, Khalid Sheikh Mohammed ati Ramzi Binalshibh so pe baalu kerin to je fifipagba fe lo kolu Kapitol, ki se White House lo fe kolu. Won tun so pe nibere Al-Qaeda gbimo lati fo baalu ti won ba gba lati fi kolu awon ile-ise atomu (nuclear) ki se lati kolu Gbongan Idunadura Agbayer ati Pentagonu, sugbon won pinu lati mo kolu awon ile-ise ilo agbara inu atomu "nigbayi na" nitori iberu pe ose e se ko "mo se e dari mo".[12]

Lati fipagba awon baalu wonyi, awon oludaniloro na lo ohun ija lati gun ati/tabi lati pa awon awako baalu, awon osise inu baalu ati awon arinajo. Esi iwadi lati awon ipe telifonu lati inu awon baalu na fihan pe awon afipagboko na lo obe lati gun awon osise inu baalu ati arinajo kan ninu baalu kan nibe.[13][14] Awon arinajo miran se ipe telifonu nipa lilo telifonu ati telifonu alagbeka,[15][16] won si pese ekunrere ohun to un sele, ninu re nipe awon melo kan ninu awon afipagboko wa ninu awon baalu ohun, pe ata tabi iru awon ifon kemika noxious, bi efuufu ataju tabi ifon ata je lilo, ati pe won ti fi obe gun awon.[17][18][19][20]

Igbimo 9/11 fihan pe awon oludaniloro yi ra ohun ija oloro.[21] Osise inu baalu ninu Ifoloke 11, arinajo kan ninu Ifoloke 175, ati awon arinajo ninu Ifoloke 93 so pe awon afipagboko na ni bombu, sugbon ikan ninu awon arinajo so pe ohun ro pe awon bombu yi ki se gidi. Ko si ifihan bombu ni ibi ijalule awon baalu yi, be sini Igbimo 9/11 gbagbo pe awon bombu na ki se gidi.[13]

Ninu Ifoloke 93 ti United Airlines, akoole apoti dudu fihan pe awon osise inu baalu ati awon arinajo gbiyanju lati gba idari baalu na latowo awon afipagboko leyin ti won gbo pelu ipe telifonu pe awon baalu afipagba bi baun na ti je fifikolu ile laaro ojo na.[22] Gege bi iwe adako ero akoole Ifoloke 93 se fihan, ikan ninu awon afipagboko pase lati yi baalu na leyin to ti han si pe won yio pofo idari baalu na si awon arinajo.[23] Laipe leyin eyi, baalu na jalule sori papa nitosi Shanksville ni Stonycreek Township, Somerset County, Pennsylvania, ni ago 10:03:11 a.m. asiko ibe (4:03:11 UTC). Khalid Sheikh Mohammed, olusagbajo awon isele yi, so ninu iforowanilenuwo ni 2002 pelu Yosri Fouda pe ibi ti Ifoloke 93 fe lo kolu ni Kapitol, ti won fun ni oruko amioro "Eka-eko eto Ofin".[24]

Ile meta to je ti Gbongan Idunadura Agbaye wo lule nitori ikuna afidimule lojo isele yi.[25] Ile to wa ni guusu (2 WTC) wo lule ni ago 9:59 laaro, leyin to jona fun iseju 56 ninu ina ti ikolu baalu Ifoloke 175 ti United Airlines fa.[25] Ile to wa ni ariwa (1 WTC) wo lule ni ago 10:28 laaro, leyin igba to jona fun bi iseju 102.[25] Nigbati ile 1 wo lule, jagbajanti to fon sori Ile 7 Gbongan Idunadura Agbaye to wa ni tosi re (7 WTC) fa ibaje si, o si je ko gbana je. Ina yi jo fun opo wakati, o si fa ibaje si isokan ifidimule ile na to mu lati wo loke ni ago 5:20 nirole to si je ki o wo lule patapata ni ago 5:21 nirole.[26][27]

Awon isele yi fa idojuru pupo larin awon agbajo oniroyin ati awon oludari irinna ofurufu kakiri orile-ede Amerika. Gbogbo irinajo kariaye pelu baalu je fifofinde fun ojo meta lati bale sorile Amerika.[28] Awon baalu to si n fo lowo nigbana je didarpada tabi titundidari si papa baalu ni Kanada tabi Meksiko. Isun iroyin segbejade iroyin tikolesenle tabi ti won tako ra won kakiri ojo na. Eyi gbalejulo ninu won so pe oko bombu kan ti be ni ibujoko Ile-ise Alakoso Oro Okere Amerika ni Washington, D.C.[29] Leyin ti won ti koko royin nipa ikolu ni Pentagonu, awon ile-ise amohunmaworan iroyin tun royin fun gbadie pe ina ti n ja ni National Mall.[30] Another report went out on the Associated Press wire, claiming that a Delta Air Lines airliner—Flight 1989—had been hijacked. This report, too, turned out to be in error; the plane was briefly thought to represent a hijack risk, but it responded to controllers and landed safely in Cleveland, Ohio.[31]


Remove ads

Itokasi

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads