Afghanístàn
From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
Afghanístàn ( /æfˈɡænᵻstæn,_æfˈɡɑːnᵻstɑːn/; Pashto/Dari: افغانستان, Pashto: Afġānistān [avɣɒnisˈtɒn, ab-],[lower-alpha 1] Dari: Afġānestān Àdàkọ:IPA-fa), àlòṣiṣẹ́ bíi Orílẹ̀-èdè Olómìnira Onímàle ilẹ̀ Afghanístàn, ni is a orílẹ̀-èdè onílẹ̀bodè ní Gúúsù àti Àrin Ásíà. Afghanístàn ní bodè mọ́ Pakistan ní ìlà-òrùn àti ní gúúsù;[lower-alpha 2] mọ́ Iran ní ìwọ̀-òrùn; mọ́ Turkmenistan, Uzbekistan, àti Tajikistan ní àríwá; àti mọ́ Ṣáínà ní àríwá-ìlàòrùn. Gbogbo ilẹ̀ ibẹ̀ fẹ̀ tó 652,000 square kilometers (252,000 sq mi), orílẹ̀-èdè olókè ní tó ní ilẹ̀ pẹpẹ ní apá àríwá àti gúúsù-ilàòrùn. Kabul ni olúìlú àti ilú tótóbijùlọ níbẹ̀. Iye aráàlú ibẹ̀ fẹ́ ẹ̀ pọ̀ tó 32 mílíọ́nù, tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà àwọn Pashtun, Tajik, Hazara àti Uzbek.
Nínú ètò ìkànìyàn 1995, àwọn ènìyàn tí wọ́n sọ pé ó wà ní ìlú yìí lé díẹ̀ ní mílíònù mọ́kànlélógún (21,017.000). Èdè tí wọ́n ń sọ ní ìlú yìí tó àádọ́ta ṣùgbọ́n ìlàjì nínú àwọn tí ó wà ní ìlú náà ni ó ń sọ páṣítọ̀ (Pashto) tí òun àti Dárì jọ jẹ èdè ìjọba (official language). Dárì (Dari) yìí nì orúkọ tí wọ́n ń pe Persian (Pásíà) ní Afuganísítàànù. Dárí yìí ṣe pàtàkì gan-an ni gẹ́gẹ́ bí èdè tí ìjọba ń lò (lingua franca). Fún ti òwò tí ó jẹ mọ gbogbo àgbáyé, èdè Gẹ̀ẹ́sì ti ń gbilẹ̀ sí i. Àwọn èdè mìíràn tí wọ́n ń sọ ní ìlú yìí ni Tadzhik, Uzbek, Turkmen, baluchi, Brachic àti pashayi
![]() |
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Remove ads
Itokasi
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads