Siẹrra Léònè

From Wikipedia, the free encyclopedia

Siẹrra Léònè
Remove ads

Siẹrra Léònè (play /sˈɛrə lˈn/) (Krio: Sa Lone), lonibise bi Orile-ede Olominira ile Siẹrra Léònè, je orile-ede ni Iwoorun Afrika. O ni bode mo Guinea si ariwa ati ilaorun, Liberia ni guusuilaorun, ati Okun Atlantiki ni iwoorun ati guusuiwoorun. Sierra Leone ni aala ile to 71,740 km2 (27,699 sq mi)[1] ao si ni olugbe ti idiye re je egbegberun 6.5. O je Imusin Britani tele, loni o ti di orile-ede olominira albagbepo to ni awon igberiko meta ati Western Area; awon wonyi na si tun je pipin si agbegbe merinla.

Quick facts Orílẹ̀-èdè Olómìnira ilẹ̀ Siẹrra LéònèRepublic of Sierra Leone, Olùìlú àti ìlú tótóbijùlọ ...

Sierra leone ni ojuojo olooru, pelu ile ayika to je orisirisi lati savannah de rainforests.[2] Freetown ni oluilu, ilu totobijulo ati gbongan okowo re. Awon ilu pataki yioku na tun ni Bo, Kenema, Koidu Town ati Makeni.[1]

Geesi ni ede onibise nibe,[3] ti won unlo ni ile-eko, ibise ijoba ati latowo awon amohunmaworan. Mende ni ede gbangba ti won unso ni guusu, beesini Temne ni ede ti ariwa. Krio (ede Krioli lati inu ede Geesi ati opo awon ede Afrika to si je ede abinibi fun awon Krio Sierra Leone) ni ede akoko ti awon bi 10% olugbe unso sugbon bi 95% ni ede na ye.[4] Botilejepe oun je lilo kakiri Sierra Leone, ede Krio ko ni ipo onibise kankan nibe.

Sierra Leone lonibise je ile fun awon eya eniyan merinla, ikookan won ni ede ati asa ti re. Awon eya eniyan titobijulo meji ni won wa, awon wonyi ni awon Mende ati awon Temne, ikokan won je 30% olugbe. Awon Mende poju ni agbegbe Guusu-Apailaorun Sierra Leone beesini awon Temne poju si ni Apaariwa Sierra Leone. O ti pe ti awon Mende ti un bori ninu oselu ni Sierra Leone. Opo awon omo-orile-ede je kiki elesin Musulumi, botilejepe won ni awon elesin Kristi bi 35%. Niyato si opo awon omo-orile-ede Afrikan miran, Sierra Leone ko ni isoro eya tabi esin bo se wa nibo miran.

Remove ads

Itokasi

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads