Ìpínlẹ̀ Taraba

Ìkan lára àwọn ìpínlẹ̀ ní orílé-èdè Nàìjíríà From Wikipedia, the free encyclopedia

Ìpínlẹ̀ Taraba
Remove ads

Taraba (Fula: Leydi Taraba 𞤤𞤫𞤴𞤣𞤭 𞤼𞤢𞤪𞤢𞤦𞤢) jẹ́ ìpínlẹ̀ ní àríwá-ìlà-oòrùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, tí wọ́n sọọ́ ní orúkọ ní ìbámu pẹ̀lú odò Taraba ní èyí tí ó sàn jákèjádò gúúsù ìpínlẹ̀ náà. Olú-ìlú ìpínlẹ̀ Taraba ni Jalingo. Púpọ̀ àwọn olùgbe rẹ̀ ni Mumuye, Fulani, Jenjo, Wurkum, àti àwọn ẹ̀ya Kona ti wọ́n gbilẹ julọ apá àríwá ìpínlẹ̀ náà. Nígbàtí Jukun, Chamba, Tiv, Kuteb àti Ichen tí wọ́n ṣàwárí pé wọ́n gbilẹ̀ júlọ ní apá gúúsù ìpínlẹ̀ náà. Àárín gọ́gọ́tà ìpínlẹ̀ náà ni ó kún jùlọ fún àwọn ènìyàn Mambila, Chamba, Fulani àti Jibawa. Ó lé ní oríṣi ẹ̀yà mẹ́tàdìnlọ́gọ́rin, àti àwọn èdè wọn ní ìpínlẹ̀ Taraba.

Quick Facts Taraba, Country ...
Remove ads

Ìtàn

Ìpínlẹ̀ náà ni wọ́n dá sílẹ̀ látara ìpínlẹ̀ Gongola tẹ́lẹ̀ rí ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹ́jọ ọdún 1991, látọwọ́ ìjọba ológun ti Ọ̀gágun Ibrahim Babangida.

Geography

Thumb
Donga River, Taraba state

Ìpínlẹ̀ Taraba ní ìsopọ̀ ní ìwọ̀ oòrùn pẹ̀lú ìpínlẹ̀ Nasarawa àti ìpínlẹ̀ Benue, ní àríwá ìwọ̀ oòrùn pẹ̀lú ìpínlẹ̀ Plateau,ni àríwá pẹ̀lú ìpínlẹ̀ Bauchi àti ìpínlẹ̀ Gombe,ní àríwá-ìlà-oòrùn pèlú ìpínlẹ̀ Adamawa, àti sí gúúsù pẹ̀lú agbègbè àríwá ìwọ̀ oòrùn ní Cameroon.

Àwọn Benue, Donga, Taraba àti Ibi ni àwọn odò ní Ìpínlẹ̀ náà. Wọ́n ṣẹ̀ wá láti àwon orí-òkè Cameroon, tí ó fẹ́ ẹ̀ sàn gba gbogbo Ìpínlẹ̀ náà ní àríwá àti gúúsù tààrà lọ inú River Niger.

Remove ads

Àwọn Ẹkùn Ìjọba Ìbílẹ̀

Ìpínlẹ̀ Taraba ṣàkónú àwọn Ẹkùn Ìjọba Ìbílẹ̀ mẹ́rìndìnlógún(LGAs). Tí àwon alága tí wọ́n dìbò yàn máa ń ṣàkóso wọn.Àwọn sì nìwọ̀nyì:

  • Ardo Kola
  • Bali
  • Donga
  • Gashaka
  • Gassol
  • Ibi
  • Jalingo
  • Karim Lamido
  • Kurmi
  • Lau
  • Sardauna
  • Takum
  • Ussa
  • Wukari
  • Yorro
  • Zing

Àwọn èdè

Àtòpọ̀ àwọn èdè ní Ìpínlẹ̀ Taraba látọwọ́ Àwọn Ẹkùn Ìjọba Ìbílẹ̀:[4]

More information LGA, Languages ...

Ussa. èdè Kuteb

Àwọn ede miiran ti wọn sọ ní ìpínlẹ̀ Taraba nìwọ̀nyí Akum, Bukwen, Esimbi, Fali of Baissa, Jiba, Njerep, Tha, Yandang, Yotti, Ywom.[4]

Remove ads

Àwọn Àwòrán

Àwọn èèyàn jànkànjànkàn

  • Aisha Jummai Al-Hassan (Mama Taraba) - Mínísítà fún ètò àwọn obìnrin ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, aṣojú ilé ìgbìmọ̀-aṣòfin fún ẹkùn àríwá Taraba tẹlẹ̀rí
  • Emmanuel Bwacha - Aṣojú ilé ìgbìmọ̀-aṣòfin fún ẹkùn gúúsù Taraba, Igbakeji apàṣẹ aṣojú ilé ìgbìmọ̀-aṣòfin
  • Theophilus Danjuma - Ọmọ-ogun orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Òṣèlú, Olókoòwò, Ọ̀gágun àgbà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà (1975-1979), Mínísítà fún ètò àbò (1999-2003)
  • Darius Ishaku - Gómìnà ìpínlẹ̀ Taraba lọ́ọ́lọ́ọ́
  • Saleh Mamman, Mínísítà fún iná-mọ̀nàmọ́ná ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà
  • Mahmud Mohammed - Adájọ́ àgbà fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà
  • Jolly Nyame - Gómìnà ìpínlẹ̀ Taraba tẹ́lẹ̀rí
  • Danbaba Suntai - Gómìnà ìpínlẹ̀ Taraba tẹ́lẹ̀rí
  • Yusuf Abubakar Yusuf - Aṣojú ilé ìgbìmọ̀-aṣòfin fún sẹ́ńtírà Taraba, Ọmọ ẹgbé òṣèlú "All Progressive Congress(APC),Caretaker/Extraordinary Convention Planning Committee "(CECPC)
  • Shuaibu Isa Lau - Aṣojú ilé ìgbìmọ̀-aṣòfin fún ẹkùn àríwá Taraba
Remove ads

References

Itokasi

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads