Ìpínlẹ̀ Bẹ́núé

Ìkan lara àwon ìpínlè ní orílè-èdè Nàìjirià From Wikipedia, the free encyclopedia

Ìpínlẹ̀ Bẹ́núémap
Remove ads

Ìpínlẹ̀ Benue jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìpínlẹ̀ ní agbègbè àríwá àáríngbùngbùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà pẹ̀lú ènìyàn tí ó tó mílíọ́nnù mẹ́rinlé-ní-ìdámẹ́rin gẹ́gẹ́ bí àbájáde ọdún 2006. Wọ́n dá ìpínlẹ̀ náà sílẹ̀ ní ọdún1976[4] láàárín àwọn ìpínlẹ̀ méje tí wọń dá lẹ̀ nígbà náà. Ìpínlẹ̀ náà gba orúkọ rẹ̀ látara odò Benue tí ó jẹ́ odò ẹlẹ́ẹ̀kejì tí ó gbòòrò jù ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[5] Ìpínlẹ̀ náà pín ààlà pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Nasarawasí àríwá; Ìpínlẹ̀Taraba sí ìlà-oòrùn; Ìpínlẹ̀ Kogi sí ìwọ̀-oòrùn; Ìpínlẹ̀ Enugu sí gúúsù-ìwọ̀-oòrùn; Ìpínlẹ̀ Ebonyi àti Ìpínlẹ̀ Cross-Rivers sí gúúsù; ó sì tún pín ààlà pẹ̀lú orílẹ̀ èdè Cameroon sí gúúsù-ìlà-oòrùn.[6] Ó ní àwọn olùgbé tí àwọn tí ó gbilẹ̀ jùlọ jẹ́ àwọn ará Tiv, Idoma àti Igede. Àwọn ọ̀wọ́ ẹ̀yà yòó kù ní Benue nìwọ̀nyí Etulo, Igbo, Jukunpeoples abbl. Olú-ìlú rẹ̀ ni Makurdi.[7] Benue lọ́lá nínú lágbègbè ọ̀gbìn; tí ó sì jẹ́ ìlú-mọ̀ọ́ká nínú ọ̀gbin: ọsàn, máńgòrò, ọ̀dùnkún, ẹ̀gẹ́, soya bínǹsì, ọkàabàbà, ẹ̀gúsí, iṣu, sesame, ráìsì, ẹ̀pà, àti Igi ọ̀pẹ.

Quick Facts Ipinle Benue, Country ...


Wọ́n sọ Ìpínlẹ̀ Benue ní ìbámu pẹ̀lú odò Benue wọ́n sì ṣẹ̀dá ẹ̀ látara Ìpínlẹ̀ Benue-Plateau tẹ́lẹ̀rí ní ọdún 1976, ní ìbárìn pẹ̀lú Igala àti àwọn apákan Ìpínlẹ̀ Kwara.[8] ní ọdún 1991, àwọn agbègbè ní Ìpínlẹ̀ Benue (pàápàá jùlọ àwọn agbègbè tí wọ́n ti ń sọ Igala), ní ìbárìn pẹ̀lú àwọn agbègbè ní Ìpínlẹ̀ Kwara State, ni wọ́n dá yọ jáde láti di apá titun ní Ìpínlẹ̀ Kogi. Àwọn ará Igbo ni a lè rí ní àwọn agbègbè ààlà àwọn agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ bíi Obi, Oju abbl.

Remove ads

Itokasi

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads