Àsìkò

From Wikipedia, the free encyclopedia

Àsìkò
Remove ads

Àsìkò tabi àkókò jẹ́ ìgbésẹ̀ ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé tí kò ṣe é yí padà láti ìgbà tí a kò mọ̀ sí àsìkò tí a wà lọ́wọ́ tí yóò sì tún yí wọ ọjọ́ iwájú tí kò tíì dé.[1][2][3]

Thumb
Ago apo, eyi je iwon fun asiko to ti re koja

Bí a bá wo ṣàkun gbogbo ìtàn pátá, a ó ri wípé ipa pàtàkì ni àkókò tàbí àsìkò kó; yálà nínú ẹ̀sìn, ìròrí tàbí ìmọ̀ ọgbọ́n inú tí a ń pè ní sáyẹ́nsì. Agogo tàbí àsìkò ni wọ́n tún fi ń ṣòdiwọ̀n lọ́dọ̀ àwọn onímọ̀ tekinọ́lọ́jì, bákan náà ni àsìkò kíkà ṣe kókó nínú ètò ìrìnà ilẹ̀ àti ti òfurufú. Bákan náà ni àsìkò ṣe pàtàkì nínú àwùjọ pẹ̀lú bí wọ́n ṣe fi ń ṣòdiwọ̀n ọrọ̀-ajé; èyí ni ó mú àwọn ènìyàn sọ wípé (owó ni àsìkò). Àsìkò yí náà ni wọ́n fi ń ní ìmọ̀sìlára ìgbà, ọ̀jọ́ orí àti ọjọ́ ayé.

Remove ads

Oríkì àsìkò

Àsìkò túmọ̀ sí onírúurú ǹkan lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn, bákan náà ni ó ní ìtumọ̀ oríṣiríṣi nínú iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan. Èyí ni kòjẹ́ kí àwọn onímọ̀ lè sọ ní pàtó wípé báyìí ni àsìkò ṣe jẹ́ tàbí oríkì báyí ni ó tọ́ kí a fún àsìkò.[4][5][6] Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé, agbọn ìmọ̀ eré ìdárayá, okòwò, iléṣẹ́ ńlá ńlá, sáyẹ́nsì tí ó fi mọ́ àwọn eléré ìtàgé ni wọ́n kò lè koyán àsìkò kéré.[7][8][9] Tí a bá wá ní kí a fún àsìkò ní oríkì kan, a ní láti ṣàkíyèsí: ìwòye ojú ọjọ́, yálà Òòrùn tàbí òṣùpá àti lílọ-bíbọ̀ sánmọ̀.

Remove ads

Itokasi

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads