Timo Werner
From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
Timo Werner (Pípè nì Jẹ́mánì: [ˈtiːmoː ˈvɛɐ̯nɐ];[4][5] tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹfà oṣù kẹta ọdún 1996, ( 6th March 1996) jẹ́ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá ọmọ orílẹ̀-èdè Germany tí ó ń gbá bọ́ọ̀lù-jẹun lórílẹ̀-èdè Gẹ̀ẹ́sì fún ìkọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá Chelsea.

Werner bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá jẹun gẹ́gẹ́ bí agbábọ́ọ̀lù-sáwọ̀n fún ìkọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù VFB Stuttgart lọ́dún 2013, òun sìn ni ọ̀dọ́mọdé tó kéré jù lọ láti kọ́kọ́ bá àwọn ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù náà díje gẹ́gẹ́ bí agbábọ́ọ̀lù-sáwọ̀n. Nígbà tí ó di ọdún 2016, Werner dara pọ̀ mọ́ ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù RB Leipzig lọ́mọ ogún ọdún, òun sìn ní ìkọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá yìí kọ́kọ́ rà tí owó rẹ̀ wọ́n tó €10 million, owó ìlú òyìnbó. Bẹ́ẹ̀ náà, òun ni ọmọdé àkọ́kọ́ tí ó kópa nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 159 àti 200 nínú ìdíje bọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá àgbábuta tí orílẹ̀ èdè Germany. Bákan náà, Werner ni agbábọ́ọ̀lù-sáwọ̀n kejì tó gbá bọ́ọ̀lù sáwọ̀n jùlọ nínú ìdíje àgbábuta tí orílẹ̀ èdè Germany lọ́dún 2019 sí 2020, kí ó tó dára pọ̀ mọ́ ìkọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá Chelsea.
Remove ads
Àwọn ìtọ́kasí
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads