Victoria Island, Lagos

From Wikipedia, the free encyclopedia

Victoria Island, Lagos
Remove ads

Victoria Island (VI) tí a lè ṣògbufọ̀ lédè Yorùbá sì Erékùṣù Victoria jẹ́ àgbègbè tó gbajúmọ̀ nílùú Èkó ní ìjọba-ìbílẹ̀ Etí-osà, ní ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ àgbègbè tí omi ọ̀sà àti òkun yíká, àwọn olówó àti gbajúmọ̀ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lo ń gbé tàbí ní dúkìá ní ìbẹ̀. Erékùṣù Victoria fẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú Erékùṣù Ẹ̀kọ́, Ìkòyí àti Lẹ̀kí. Victoria Island ni a lè pè ní olú-ìlú okowò àti ìsúnná-owó nílùú Èkó nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ olú-ilé-ìṣe ló tẹ̀dó síbẹ̀.[1] [2]

Thumb
Civic Center, Victoria Island

Victoria Island jẹ́ agbègbè ọlọ́rọ̀ tí ó yíká erékùṣù àtijọ́ ti orúkọ kan náà tí ó wà nítòsí ibi tí a mọ̀ sí Lagos Island, Ikoyi àti Lekki Peninsula ní ẹ̀bá adágún Èkó. Ó jẹ́ ilé-iṣẹ́ ìṣòwò àkọ́kọ́ àti ilé-iṣẹ́ ìnáwó ti Ìpínlẹ̀ Èkó, Ilẹ̀ Nàìjíríà. Victoria Island jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn agbègbè ìyasọ́tọ̀ jùlọ àti agbègbè tó gbówólórí láti gbé ní Ìlú Èkó. Ìlú àti erékùsù wà láàrin àwọn ààlà tí ìjọba ìbílẹ̀ Eti-Osa (LGA).[3][4]

Remove ads

Ọ̀rọ̀ Ajé Ìlú Náà

Thumb
The Access Bank tower, Victoria Island

Ibi ìfowópamọ́ ti Guaranty Trust Bank àti Access Bank plc ní olú ilé-iṣẹ́ wọn lórí erékùṣù náà, Halliburton àti IBM ṣiṣẹ́ àwọn ọ́fíìsì lórí Victoria Island.[5][6][7]

Ìwolulẹ̀ Ìlú Maroko

Àwọn olùgbé ìlú Maroko tẹ́lẹ̀ tí a fipa sì tì lépa àtúnṣe láàrín ètò ìdájọ́ Nàìjíríà, láìsí àṣeyọrí. Ní ọdún 2008, àjọ kan tó ń jẹ́ ẹ̀tọ́ ọmọnìyànèyí tí a mọ̀ sí human rights, Social and Economic Rights Action Centre (SERAC), fi ẹ̀sùn kan ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àti Ènìyàn nílẹ̀ Áfíríkà fún àwọn ará Maroko.

Ilé-ìwé

British International School Lagos,[8] àti Lycée Francais Louis Pasteur de Lagos wà lórí Victoria Island.[9] Èyí tó tún wà lórí Victoria Island yìí náà ni American International School of Lagos,[10]

Àwọn Ìtọ́kasí

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads