Viola Davis

From Wikipedia, the free encyclopedia

Viola Davis
Remove ads

Viola Davis ( /vˈl.ə/; tí a bí ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹjọ, ọdún 1965) jẹ́ òṣèrébìnrin ilẹ̀ Amerika. Ó ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì-ẹ̀yẹ bíi Academy Award, Primetime Emmy Award àti àmì-ẹ̀yẹTony méjì. Ó sì tún jẹ́ ọmọ african American tó gba Triple Crown of Acting.[1] Ìwé ìròyìn Times ṣe àfihàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ọ̀kan lára àwọn ọgọ́rùn-ún obìnrin tó gbajúmọ̀ jù ní ọdún 2012, 2017,[2][3] àti ní 2020, The New York Times fi sí ipò kẹsàn-án, lára òṣèré tó lọ́lá jù lọ.[4][5]

Quick facts Ọjọ́ìbí, Iléẹ̀kọ́ gíga ...

Davis bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ ní Central Falls, Rhode Island, níbi tí ó ti ń ṣe eré orí-ìtàgé. Lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè láti ilé-ìwé Juilliard ní ọdún 1993, ó gba àmì-ẹ̀yẹ Obie ní ọdún 1999 fún ẹ̀dá-ìtàn rẹ̀, tó ṣe Ruby McCollum nínú Everybody's Ruby.

Remove ads

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀

Wọ́n bí Davis ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹjọ, ọdún 1965 ní St. Matthews, South Carolina, sínú ìdílé Mae Alice Davis (née Logan) àti Dan Davis.[6][7][8] Inú ọgbà ìyá-ìyá rẹ̀ ni wọ́n bi sí.[9] Bàbá rẹ̀ jẹ́ aṣọ́gbà fún ẹṣin, ìyá rẹ̀ sì ń ṣiṣẹ́ ní ilé-iṣẹ́ kan.[10] Òun ni ọmọ karùn-ún, láàárín ọmọ mẹ́fà tí òbí rẹ̀ bí.[11] Ìgbà díẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bí i, àwọ òbí rẹ̀ kó lọ sí Central Falls, Rhode Island.[8]

Ìyá rẹ̀ tún jẹ́ ajà-fẹ́tọ̀ọ́-ọmọnìyàn.[10] Nígbà tí ó wà ní ọmọdún méjì, wọ́n òun àti mú ìyá rẹ̀ lọ sẹ́wọ̀n lẹ́yìn tí àwọn ọlọ́pàá mú wọn níbi ìwọ́de kan.[12] Ó sọ ọ́ di mímọ̀ pé inú ìṣẹ́, òṣì àti ìyà ni òun gbé dàgbà,[13] ó ròyìn bí wọ́n ṣe ń gbé nílé tó pọ̀ fún eku àti agbèbè tí àwọn ènìyàn ti pa tì.[14] Davis tan mọ́ gbajúgbajà òṣèré Mike Colter, tí àwọn ènìyàn mọ̀ fún eré apanilẹ́rìn-ín rẹ̀ Marvel Comics tí ẹ̀dá-ìtàn rè sì jẹ́ Luke Cage.

Davis lọ ilé-ìwé Central Falls High School. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀jẹ̀-wẹ́wẹ́, ó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ TRIO Upward Bound àti TRIO Student Support Services programs. Ó tún forúkọ sílẹ̀ fún Young People's School fún iṣẹ́ tíátà kan ní West Warwick, Rhode Island. Bernard Masterson tó jẹ́ olùdarí ẹgbé náà ló ṣàwárí ẹ̀bùn Davis níbi ìpàdé náà[15]

Lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè láti ilé-ìwé girama, Davis lọ sí Rhode Island College, níbi tí ó ti ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa iṣẹ́ tíátà. Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ilé-ìwé Juilliard, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ fún ọdún mẹ́rin[10] ó sì jé ọ̀kan láara àwọn ọmọ-ẹgbé dírámà kan "Group 22" (láti ọdún 1989 sí ọdún 1993).

Thumb
Davis at the 2015 Screen Actors Guild Awards
Remove ads

Ayé rẹ̀

Davis fẹ́ ọṣèrékùnrin Julius Tennon ní oṣù kẹfà, ọdún 2003. Ní ọdún 2011, wọ́n gba ọmọ kan tó, orúkọ ọmọ náà sì ni Genesis. Davis tún jẹ́ ìyá fún àwọn ọmọ méjì tí Tennon bí nínú ìgbéyàwó rè tẹ́lẹ̀.[16]

Davis jẹ́ onígbàgbọ́ tó máa ń lọ ilé-ìjọsìn Oasis tó wà ní Los Angeles lóòrè-kóòrè.[17]

Àwọn fíìmù rẹ̀

  • Doubt (2018)
  • The Help (2011)
  • Prisoners (2013)
  • Get On Up (2014)
  • Lila & Eve (2015)
  • Suicide Squad (2016)
  • Fences (2016)
  • Widows (2018)
  • Ma Rainey's Black Bottom (2020)
  • The Suicide Squad (2021)
  • The Woman King (2022)

Àtòjọ àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀

  • 81st Academy Awards, Best Actress in a Supporting Role, nomination, fún Doubt (2008)
  • 84th Academy Awards, Best Actress in a Leading Role, nomination, fún The Help (2011)
  • 89th Academy Awards, Best Actress in a Supporting Role, win, fún Fences (2016)[lower-alpha 1]
  • 93rd Academy Awards, Best Actress in a Leading Role, nomination, fún Ma Rainey's Black Bottom (2020)[lower-alpha 2]

Àwọn ìtọ́kasí

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads